Salakọ-Oyedele lo sọrọ naa nibi eto ọlọdọọdun nni ti wọn fi n ṣayajọ aṣilo oogun, ati bio wọn ṣe n gbe e lọna ti ko tọ, ey9i ti ajọ agbaye nni maa n ṣagbatẹru ẹ, iyẹn (United Nations’ International Day Against Drug Abuse and Illicit Drug Trafficking).
Eto tọdun yi ni wọn pe akori ẹ ni "Health for Justice, Justice for Health’’ ni ajọ to n ri si aṣilo oogun, National Drug Law Enforcement Agency, ẹka ti Idiroko ṣagbatẹru ẹ, nibẹ ni igbakeji Gomina ti sọ pe igbesẹ ti n lọ lati fọwọsowọpọ pẹluu awọn ile-iṣẹ adani lati ri i epe wọn n gba awọn ọdọ siṣẹ, eyi ti ko nii faaye silẹ fun wọn lati maa lo aṣilo oogun, tabi egbogi oloro to n ṣakoba fun agọ ara.
O jẹ ko di mimọ pe airiṣẹ ṣe awọn ọdọ lo sun wọn de ibi ki wọn maa fa igbo, mu gbana, ṣiṣa, kokeeni atawọn nnkan min in to n ṣe ẹya ara nijamba, ati pe bi wọn ba ri iṣẹ ṣe, wọn ko nii pada sidi ẹ mọ.
Ṣaaju ninu ọrọ rẹ, adari ajọ NDLEA lẹka Idiroko, Arabinrin Ibinabo Archie-Abia sọ pe aṣilo oogun ati gbigbe e ti ṣakoba fun ọpọlọpọ idile, to si ti ba ọjọ ọla awọn ọdọ jẹ, eyi to jẹ ki wọn maa huwa jagidijagan kaakiri igboro.
No comments:
Post a Comment