Iroyin ibanujẹ to tun n lọ kaakiri igboro, paapaa agboole amuludun bayii ni ti gbajugbaja agba oṣere tiata nni, Jide Ogungbade to jade laye lọjọ Iṣẹgun to kọja yi.
A gbọ pe lẹyin aimọye oṣu ni baba naa ti wọn bi lọjọ kọkanlelogun oṣu kẹjọ ọdun 1952 ti lo lọsibitu kan niluu Eko ko too ki aye pe o digboṣe.
Lara awọn mọlẹbi oloogbe naa, Pasitọ Niyi Gbade ati Ayọtade Ogungbade ni wọn kede iku ọmọ bibi iluu Akoko-Ikarẹ nipinlẹ Ondo naa sita fawọn eeyan.
No comments:
Post a Comment