Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, inu ẹdun ọkan bayii ni ọkan lara awọn oṣiṣẹ alaabo ti So Safe Corp nipinlẹ Ogun labẹ ọga wọn Sọji Ganzallo wa bayii, latari bi wọn ṣe padanu ọkan lara awọn oṣiṣẹ wọn, Kẹhin Aigbeṣe dagbere faye lẹyin oṣu kan gbako tawọn adigunjale yinbọn fun un niluu Abẹokuta.
Ṣe lọrọ di bolo o yago lọjọ
Mọnde ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹfa ọdun yi ladugbo kan ti wọn n pe ni Ọlọrunṣogo mọ Oke-Lantoro niluu
Abẹokuta nigba ti wọn lawọn adigunjale atawọn oṣiṣẹ alaabo So Safe Corps
nipinlẹ Ogun doju ija kọ ara wọn.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ni nnkan bi
aago mejila aabọ ooru la gbọ pe awọn adigunjale ya wọ adugbo Ọlọrunṣogo mọ
Oke-Lantoro, ti wọn si bẹrẹ sii jawọn eeyan lole pẹluu ibọn. A gbọ pe lara awọn
kan ti wọn wa ladugbo naa ni wọn ta awọn oṣiṣẹ So Safe yi lolobo, ti wọn si
gbera lati lọọ koju wọn.
Wọn ni bawọn adigunjale yi ṣe
rii pe awọn oṣiṣẹ So Safe ti wa layika, ni wọn ti ba ẹsẹ wọn sọrọ. Nibi ti wọn
lawọn oṣiṣẹ So Safe naa ti n wa wọn lati ri wọn mu la gbọ pe wọn ti mu ọkan
lara wọn lati ọwọ ẹyin.
Ibi ti wọn ni oṣiṣẹ So Safe ti
wọn pe orukọ ẹ ni Kẹhinde Aigbe, ẹni ọdun mejidinlaadọta ati adigunjale naa ti
wọya ija la gbọ pe ọkan lara awọn adigunjale ti ri wọn, ti wọn loo si ṣọ Kẹhinde daadaa, ko too yinbọn fun nikun.
Ọrọ naa di pẹntuka nigba ti wọn
lawọn oṣiṣẹ So Safe naa tun yawọ agbegbe naa, ko too di pe gbogbo awọn
adigunjale yi na papa bora, loju ẹsẹ ni wọn ti gbe Kẹhinde lọ si ọsibitu FMC to
wa nitosi fun itọju.
Wọn ni kani wọn lo iṣẹju marun
ki wọn too gbe Kẹhinde de ọsibitu yi ni, o ṣee ṣe ko dakẹ, ati pe ajẹsara ti
wọn loo wa lara ẹ ni ko jẹ ko ku soju ogun.
Agbẹnusọ So Safe, Ọgbẹni Mọruf Yusuf lasiko to n gbe iṣẹlẹ naa si AWIKONKO leti sọ pe ara ko nii rokun, bẹẹ ni ara ko nii ro adiẹ mọ bayii laarin awọn
atawọn adigunjale nipinlẹ Ogun nitori pe awọn ti tunra mu lati maa koju awọn ọdaran naa lọna igbalode.
Bẹẹ lo gbawọn araalu lamọnran
pe ki wọn ma ṣe dẹkun lati maa tete ta ileeṣẹ awọn lolobo nitori pe eto aabo
ipinlẹ Ogun lo jẹ ẹgbẹ wọn logun.
Bakan naa lo tun jẹ ko ye wa pe awọn ti ṣe ojuṣe awọn lori iku Kẹhinde, nitori pe adanu nla lo jẹ fawọn to si gbadura pe Aṣẹda yoo bu ororo itura sawọn mọlẹbi oloogbe naa lọkan
Bakan naa lo tun jẹ ko ye wa pe awọn ti ṣe ojuṣe awọn lori iku Kẹhinde, nitori pe adanu nla lo jẹ fawọn to si gbadura pe Aṣẹda yoo bu ororo itura sawọn mọlẹbi oloogbe naa lọkan
No comments:
Post a Comment