Igbakeji Gomina ipinlẹ Ogun, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ-Oyedele ti jẹ ko di mimọ pe lara awọn nnkan to jẹ ijọba ipinlẹ Ogun logun ju ni ti eto ilera, nitori pe igbe aye alaafia gan an lo le mu kawọn araalu wa ni irọrun, eyi tijọba si ti ṣetan lati mu ni okunkundun.
Onimọ-ẹrọ Salakọ-Oyedele lo fidi ọrọ naa mulẹ nibi ayẹyẹ ọjọ ibi Ọjọgbọn kan lẹka eto ilera, Ọjọgbọn Babatunde Lawal Salakọ, nibi ti wọn tun ti lo anfaani ẹ ṣe ifilọlẹ iwe kan, eyi to waye ninu gbọngan Ogunlesi to wa ninu ọsibitu UCh niluu Ibadan.
Lara awọn to tun wa nibẹ ni Ọlọta tiluu Ọta, Ọba Adeyẹmi Ọbalanlẹgẹ; Ọjọgbọn Ikechi Okpechi; Ọjọgbọn Isaac Adewọle; Ọjọgbọn Babatunde Salakọ, atawọn min in.
Ninu ọrọ rẹ, Ọba Ọlọta ṣapejuwe ọmọ ọlọjọ ibi naa gẹgẹ bi ẹni ọwọ to pẹluu apẹẹrẹ rere, toun si tun jẹ ọkan lara awọn to gba abẹ rẹ kọja.
No comments:
Post a Comment