ẸNI TI KO BA NI ẸMI ỌLỌRUN LO MAA SỌ PE ASIKO ỌBASANJỌ KO SAN AWỌN ỌMỌ NAIJIRIA – WOLII ABIỌDUN AKANNI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, July 7, 2019

ẸNI TI KO BA NI ẸMI ỌLỌRUN LO MAA SỌ PE ASIKO ỌBASANJỌ KO SAN AWỌN ỌMỌ NAIJIRIA – WOLII ABIỌDUN AKANNI

Gbajugba wolii nni ti aye n gba ti ẹ lasiko yi, Wolii (Dọkitọ) Innocent Abiọdun Akanni, ẹni tọpọ awọn eeyan mọ si Awikonko loju ọlọrọ ti rawọ ẹbẹ sawọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria pe ki wọn ye e bu ẹnu atẹ lu Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ mọ, tori pe oriire ti Baba naa mu wọ Naijiria ko le parẹ titi aye.
 
Wolii Abiọdun Akanni lo sọrọ naa ni ṣọọṣi ẹ to wa niluu Ṣagamu, ipinlẹ Ogun laipẹ yi nigba to n bu ẹnu atẹ lu bawọn Fulani ṣe n dukooko mọ awọn ọmọ Naijiria, paapaa ilẹ Yoruba.

Bakan naa lo tun gba Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams lamọnran lori igbesẹ to fẹ ẹ gbe lati gbogun ti iwa iṣekupani, ijinigbe ati oniruuru tawọn Fulani Darandaran mu wọ ilẹ Yoruba.

Wolii Abiọdun Akanni sọ pe “Ọjọkijọ ti ọmọ-ọkọ ba ti n ṣe bi i wi pẹ ọmọ ale loun loju aare, ọmọ ale naa ni aare ma a pe e. Awa la sọ pe Oluṣẹgun Ọbasanjọ ko dara, ṣugbọn ni gbogbo asiko ti Oloye Ọbasanjọ lo nibẹ, o lawọn nnkan to ṣe. Ẹ wo bi orilẹ-ede South Africa ṣe ri, bi Mandẹla ṣe jiya to, wọn tun fun laaye pe ko maa ṣe ijọba lọ di asiko ti ẹlẹmin ba gba a, ṣugbọn toun funra rẹ sọ pe asiko ti to foun, oun ko le ṣe e mọ, ki wọn yan ẹlomin in, ṣugbọn ni bayii, ẹ lọ wo nnkan to n ṣẹlẹ nibẹ bayii, ẹ maa ri i pe ko dabi mọ, ti South Africa ko si dara di asiko yi mọ bii ti tẹlẹ. Bi wọn ba n sọ pe Ọbasanjọ ko ṣe daradara, eeyan ti ko ba ni ẹmi Ọlọrun lo maa sọ bẹẹ.

“Ọbasanjọ ṣe daradara, to si pọ koọja afẹnusọ, bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to le rin ki ori ẹ ma min, nitori pe ko sẹni to le tẹ Naijiria lọrun rara. Bi ẹ ba wo o, diẹ lara awọn oriire ti Ọbasanjọ mu wọ Naijiria, ti a si n jẹ anfaani ẹ dasiko yi ni ẹrọ ibanisọrọ. Ẹ wo igba tawọn MTN de, o lawọn to n lo o, o si niye ti wọn n ta a siimu (SIM Card), igba to tun ya, o tun niye ti wọn n ta. Igba to tun ya, o tun ba wọn fa a titi, to si rii pe wọn ko fẹ ẹ gbọ, lo ba gbe awọn alatako dide, ti wọn si gbe ECONET dide lati ba wọn fa a, tawọn eeyan si rọ lọ sọdọ wọn. Bo tun ṣe to asiko kan, tawọn yẹn naa fẹ ẹ gbabọdi, ti wọn fẹ maa bawọn MTN fọọsowọpọ, lo ba gbe GLO dide. Okoowo ti ko ba ti si ifigagbaga, wọn maa n ṣe nnkan to ba wun wọn ni. Igba tawọn GLO de, tawọn eeyan tun rọ lọ sibẹ, paapaa ọwọ ti wọn tun gbe nigba to ya lo mu ki gbogbo ẹ bẹrẹ sii lọ silẹ.

“Ṣe ni wọn n fi siimu naa bẹ wa bayii, tori pe ko le lọ soke mọ bayii. Ọgọrun naira ni wọn ta bayii, iṣẹ ọwọ Ọbasanjọ ni. Ẹlẹẹkeji, igbe aye arunpa lawọn olukọ n gbe tẹlẹ, to jẹ pe Ọbasanjọ lo gbe ‘Gbẹnu Arẹmu’ dide, tawọn olukọni di ẹni to n kọ ile ra ilẹ, ti wọn kọ ile nla, ti wọn tun n ra mọto to wun wọn. Latigba to si ti kuro nibẹ, ko sẹni to tun ri iru ẹ ṣe mọ. Eyi to tun ya mi lẹnu ninu ọrọ ẹ, to jẹ pe asiko ko to fun un lati ṣe e, ti ko ba jẹ ẹlẹẹkẹta, to ba jẹ pe kii ṣe bo ṣe jẹ, wọn a ti gba awọn min in laaye lati wọle wa koju DSTV, owo yẹn a si ti lọ silẹ ju bo ṣe wa bayii lọ. Wọn rẹ Naijiria jẹ kọja oju ta a fi n wo o. Awọn ọmọ Naijiria naa lo wa nibẹ lọdọ wọn lọhun, tori pe oyinbo ko le de lati wa a fọwọ lalẹ fun wa nibi, nigba ko mọ bi ilu wa ṣe ri. Lẹyin ẹ, Ọbasanjọ naa lo gbe EFCC dide, owo ti wọn si gba naa ni wọn lo ninu ẹ fi kọ papa iṣere to wa l’Abuja. Awọn kan n sọ pe wọn ko mọ bi wọn ṣe ṣe owo, ṣugbọn eyi tawọn Hausa wọn gba, bawo ni wọn ṣe ṣe e.

Image may contain: 1 person 
“Ko si nnkan ti wọn tun ṣe to tun dọgba bii ti Ọbasanjọ mọ, ijọba di ẹni to n jẹ awọn olukọ lowo oṣu, ti wọn dẹni to n tọrọ jẹ. Ko dara rara, bibeli gan an sọ pe ‘ẹ san owo ọya fawọn to tọ si’. Awọn oṣiṣẹ a ṣiṣẹ, ijọba ko nii san owo mẹta, marun fun wọn. Ki lo de to jẹ pe igba ti Ọbasanjọ kuro nibẹ ni wọn ko san owo ọya fawọn oṣiṣẹ mọ.

“Ori lo gbe Baba wa Buhari debẹ, ẹni to ba si fẹẹ tun Naijiria ṣe yoo kọkọ mojuto ile ẹ na. Bi wọn ba sọ pe ki awa Yoruba ye e gbe ibọn rin kaakiri, ki lo de tawọn Hausa n gbe ibọn ati ada rin kaakiri, wọn si n sọ pe aabo lo wa fun, ọlọpaa ko si mu wọn ri. Igba ti a fi wọn silẹ naa, ko si nnkan ti mo fẹẹ sọ bi ko ṣe pe Yoruba ni wọn ko gbọdọ gbagbe sun. Ki Yoruba pada wa sile lati ronu ara wọn, ki wọn ye e ru ofin sori bii ti harahara. Awọn iran Fulani ti pinu pe awọn ni wọn a maa jẹ olori, ki Yoruba ati Ibo maa ṣe ọmọ ọdọ lẹyin wọn.

“Tori pe Yoruba ko ti i fọwọ sii pe ki Ibo maa lọ ni ko ṣe rọrun fawọn Ibo lati pin, bi Yoruba ba da si i, wọn maa kuro dandan ni. Ki onikaluku duro, kawọn Fulani, Hausa duro laaye wọn lọhun lati maa da ẹran wọn kaakiri, ki awa naa si duro laaye wa. Ko ni i si wahala, ṣugbọn ọtẹ ti a n ṣe kaakiri ni ko jẹ ka ni isinmi, ki Ọlọrun jẹ ka bọ kuro ninu ọtẹ ni.”

Nigba to n gba Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams lamọnran lori bo ṣe loun yoo dide ja fun ilẹ Yoruba, ilu mọn ọn ka wolii naa sọ pe “Bi Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams ba mọ pe oun fẹẹ ja fun ilẹ Yoruba, a jẹ pe Ọlọrun fẹ ẹ lo fun ogo kan ni, ogo orilẹ-ede si ni. Bi a ṣe bi i lo si fa, tori pe a ti bi i l’akọ ni. Akọni ni Gani Adams, to si jẹ pe Ọlọrun lo gbe e de bẹ.
 
“Mo fẹ ki Iba Gani Adams ranti pe Aarẹ Ọna Kakanfo kan lo gbe wa ṣubu nigba kan, to fi di pe awọn Fulani lo wa n paṣẹ niluu Ilọrin titi di asiko yi, Yoruba niluu Ilọrin, Ṣebi Yoruba ni Bukọla Saraki, Saraki inu orukọ ẹ ni wa a yọ kuro, yoo si jẹ ko le mọ ibi to ti wa.

“Bi Aarẹ Ọna Kakanfo ba mọ pe loootọ loun fẹẹ ja fun ilẹ Yoruba, o gbọdọ kọkọ pe gbogbo awọn agbaagba ilẹ Yoruba jokoo lati ba wọn ṣepade, ti Oloye Ọbasanjọ ko si gbọdọ gbẹyin nibẹ. Ọbasanjọ ti jagun ilẹ ri, ija ti a si fẹ ẹ ja yi, ki i ṣe ija ọrọ ibọn, bi ko ṣe ija abẹlẹ, ti yoo fun wa lanfaani lati lo agbara ilẹ Yoruba lati fi je, ko si wa a rawọ ẹbẹ si Ọlọrun ko le tii lẹyin.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI