EMI O SI NILE ỌKỌ MI O, ILE MI NI MO N GBE - MERCY AIGBE PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 22, 2019

EMI O SI NILE ỌKỌ MI O, ILE MI NI MO N GBE - MERCY AIGBE PARIWO SITA

Gbajugbaja oṣerebinrin nni, Mercy Aigbe ti sọ pe irọ nla to jinna si otitọ ọrọ ni ọkọ oun, Lanre Gẹntry n pa pe oun ti n gbe ninu ile ẹ, ati pe awọn ti pari ija wọn kuro ni kọọtu, ti ko si si wahala kankan mọ.

Lọsẹ to kọja yi ni Lanre Gentry sọ ọ nita gbangba pe ko si nnkan to n jẹ aawọ mọ laarin oun ati iyawo oun, Mercy Aigbe, ati pe awọn jọ n gbe papọ bayii ni.

Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ pe bi Mercy ṣe gbọ ọrọ ti baba ọmọ ẹ sọ yi, lo ti gba ori ayelujara rẹ ti Instagram lọ, to si lọ ọ jẹ ki gbogbo agbaye mọ pe oun ko si nile Lanre rara o.

Lanre Gentry says 
Oun o ti ẹ tun ya awọn eeyan lẹnu ni bo tun ṣe sọ pe ki lo de tawọn oniroyin ṣi n pọn ọn le lati maa lọ fọrọ wa lẹnu wo, nitori pe kii ṣe ẹni apọnle rara, idi ni yii toun ko fi pada sile rẹ, to jẹ pe ile toun fowo ara oun kọ loun n gbe.

Lanre Gentry ninu ọrọ rẹ sọ pe:
A ko si nile ẹjọ mọ, ko si si wahala kankan mọ laarin wa. Iyawo mi ni, ko si sẹjọ mọ bayii. O ti pada sile mi.
Ṣugbọn ohun ti Mercy Aigbe sọ re e:
Ki lo n ṣe Baba Juwọn to n ṣe bayii? Ati pe ki lo de tawọn eeyan ṣi n pe e lati beere ọrọ lọwọ ẹ? O ṣa n fẹ kawọn eeyan mọ oun. Ile mi ni mo n gbe o.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI