Bo tilẹ jẹ pe wọn ti foju ogbologbo ọdaran nni, Ramọni Oṣhodi bale ẹjọ, ti adajọ si ti sun igbẹjọ siwaju di ọjọkarundinlọgbọn oṣu yi, sibẹ ko tii daju pe ọdọmọkurnin naa yoo bọ ninu wahala to ko ara rẹ si yii.
Ogbologbo wọbia ti wọn loo gbona ninu ki wọn maa lu jibiti lori ayelujara ni Ramọni, ti wọn ni ko si apo ile ifowopamọ si ti ko ti le ji owo olowo gbe nibẹ, nitori iṣẹ to fi n jẹun niyẹn.
AWIKONKO gbọ pe bi Ramọni ti wọn lo gbajumọ daadaa ninu iṣẹ jibiti yi ba ti ji foonu gbe, yoo yọ kaadi inu ẹ, yoo si bẹrẹ sii fi fa owo yọ ninu apo ile ifowopamọ si wọn, afigba to ba gba gbogbo owo to ba wa nibẹ tan, ko to o jawọ, ti wọn si loo ti lu ogunlọgọ awọn eeyan ni jibiti.
Nigba taṣiri ẹ maa tu sọwọ ọlọpaa, a gbọ pe ori ọkada lọwọ ti tẹ Ramọni ti wọn lọmọdun mẹtadinlọgbọn ni lagbegbe Oṣhodi ni nnkan bi aago meje aabọ owurọ, iyẹn lasiko ti wọn lo n pada bọ lati ibi to ti lọọ ji owo gba.
A gbọ pe bi wọn se da oun ati ọlọkada ẹ duro, ni wọn ti bẹrẹ sii yẹ ara rẹ wo, ti wọn si ba oriṣiriṣi kaadi ti wọn fi n gba owo ni banki lọwọ ẹ, pẹluu kaadi foonu (SIM cards) loriṣiriṣi lapo ẹ pẹluu.
Baṣiri ṣe tu yi la gbọ pe o bẹrẹ sii bẹbẹ pe ki wọn ṣe oun jẹjẹ, ṣugbọn tawọn ọlọpaa sọ pe yoo lọ bẹbẹ nile ẹjọ.
Adajọ ko gba lati gba beeli ọdaran naa dasiko ta a kọ iroyin yi tan.
No comments:
Post a Comment