Inu ayẹyẹ nla ni idile Okoye wa titi di asiko ti a ṣakojọpọ iroyin yi tan, pẹluu bi wọn ṣe n ṣayẹyẹ ọjọ ibi ọdun meji awọn ibeji Paul Okoye.
Oni ọjọ kẹjọ, oṣu keje ni ayajọ ọjọ manigbagbe ti iyawo Paul Okoye to jẹ ilu mọn ọn ka olori takasufe (Hiphop) nni bi ibeji lanti-lanti.
Ori ikanni ayelujara ti Instagram ni gbajumọ olori naa gbe fọtọ awọn ibeji naa si, to si n ki wọn ati ara rẹ ku oriire, tawọn ololufẹ rẹ naa si n ki wọn, ko da a, wọn tun mu orin adura sẹnu pẹluu fun wọn.
No comments:
Post a Comment