Adeoye Ọlayẹmi, Ekoo
Ko si ibeere meji to n lọ
nigboro bayii, bi ko ṣe ti ọkan lara awọn gbajugba sọrọsọrọ ori redio nni,
Adewale Dada tawọn eeyan tun n pe ni "The Good" wi pe nibo lo wa lasiko yi, ti ko si tiii sẹni to le dahun ibeere naa.
Fawọn to ba mọ ọkunrin naa
daadaa, wọn yoo mọ pe ọrukọ rẹ rinlẹ daadaa ni nnkan bii ọdun mẹrin si mẹta
sẹyin sasiko yi, ṣugbọn latigba to ti gba ipo akọwe ijọba ibilẹ Ado-Odo Ọta ni
saa keji ti gomina ana, Ibikunle Amosun ṣe lo ti dabi ẹni pe orukọ rẹ ko fi bẹẹ
lu agogo mọ leti awọn araalu.
Bo tilẹ jẹ pe Gbajumọ sọrọsọrọ
naa ṣi n ṣe eto lori awọn redio bii Faaji, Sweet, OGBC ati tẹlifiṣan OGTV titi
di asiko yi, sibẹ ṣe lo dabi ẹni pe ọkunrin ti ko fi bẹẹ ga pupọ naa, to si
fẹran lati maa wọ aṣọ alawọ ewe ati funfun ni gbogbo igba naa ko jẹ aayo fawọn
ololufẹ ẹ mọ bayii, eyi ti ko si yẹ ko ri bẹẹ.
Ahesọ kan to ti ẹ ta si wa leti
laipẹ yi ni ohun ti wọn n sọ pe oṣelu lo gba iṣẹ naa lọwọ ọkunrin naa, ati pe ogbologbo
alatilẹyin Sẹnetọ Ibikunle Amosun ni, ti ko si si nnkan to le gbe e kuro lẹyin
ẹ.
Kii Sẹnetọ Ibikunle Amosun too
di Gomina ipinlẹ Ogun lọdun 2011, ko sẹni to fẹẹ gbọ sọrọsọrọ min in bi ko ṣe
Wale Dada, tawọn eeyan tun mọ si Ọmọ Iya Dada ni Mọkọlọki, latari awọn ọna to
maa n gbe iṣẹ naa gba, to si tun tayọ daadaa laarin awọn ẹgbẹ ẹ.
Ko pẹ ti Amosun wọle gẹgẹ bii
Gomina ni Wale Dada ti bẹrẹ sii polongo ara rẹ lati di alaga ijọba ibilẹ
Ado-Odo Ọta, to si maa n fi awọn eto ẹ lori redio ati tẹlifiṣan gbe Amosun
larugẹ lati wa ojurere rẹ, ko le ba a ri ipo naa gba, ṣugbọn tiyẹn ko woju ẹ
rara.
Ṣugbọn ṣe la gbọ pe awọn kan ni
wọn ba ọkunrin naa bẹbẹ Amosun nigba to tun gbe apoti ẹlẹẹkeji lati di alaga
ijọba ibilẹ, ti wọn si gba lati fun un ni akọwẹ ijọba ibilẹ naa, koun naa le ri
jajẹ pada, tori ta a gbọ pe ko fi bẹẹ si owo lọwọ ẹ mọ rara nigba naa.
Bi wọn ṣe sọ pẹ ijọba Amosun ko
tẹ awọn araalu, paapaa awọn ara Ado-Odo Ọta lọrun to, lo mu kawọn eeyan kẹyin
si Wale Dada to maa n fojuoojumọ gbe Amosun larugẹ, nitori ti wọn lawọn eeyan
mọ pe ṣe lo n tan wọn jẹ, eyi ti wọn lawọn eeyan ko fẹ.
Wọn ti ẹ ni Wale Dada gbiyanju lati mu idagbasoke diẹ bawọn agbegbe to ṣoju fun bii ko tun ọna wọn ṣe, bii ko ṣe omi fun wọn, atọn nnkan min in lasiko ẹ, to si jẹ pe lapo ara rẹ pẹluu iranlọwọ awọn kan, ṣugbọn sibẹ wọn ni ṣe lawọn eeyan tun n yinmu sii lẹyin.
A ti ẹ gbọ pe awọn araalu ti
Wale Dada ti wa gan an ko fi bẹẹ gba ti ẹ mọ lasiko yi, tori bo ṣe gbaruku ti
Ọnọrebu Adekunle Akinlade tẹgbẹ oṣelu APM ti Amosun fa kalẹ labẹ asia ẹgbẹ
oṣelu APM.
Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, Wale
Dada ṣi wa lori eto ẹ nile-iṣẹ OGTV laarọ yi pẹluu awọn isọngbe e, to si tun
ṣeto nile iṣẹ redio Sweet, ṣugbọn sibẹ, wọn lawọn eeyan kii fẹẹ gbọ ọrọ rẹ mọ
tori oṣelu to wọ, ti ko si fọlọpọ ṣe e.
Bi irọ ni, bo si jẹ otitọ, a ko
ti i le fidi ẹ mulẹ bayii, ohun ti a gbọ ni pe gbogbo ọna ni Wale Dada n wa
lati tun wa oju rere Gomina Dapọ Abiọdun to nipo bayii, ko si tun le ri ounjẹ
jẹ lasiko yi.
Wale Dada lo gbe awọn bii
Gbenga Ogundeyi tawọn eeyan mọ si Fẹlẹfẹlẹ Laye dide nidi iṣẹ orin, bo tilẹ jẹ
pe ija ni wọn fi tuka gbẹyin nigba ti adehun wọn fori ṣanpọn, tiyẹn si sa gba
iluu Ekoo lọ lọdọ puromota min in to ti n ri owo gidi bayii.
Ṣa o, ohun ti a fẹ jẹ ko ye Ọmọ
Iya Dada ni Mọkọlọki bayii ni pe, orukọ rẹ ko rinlẹ, ko si ta mọ bii ti tẹlẹ mọ,
to si gbọdọ wa nnkan ṣe sii. Imọnran tawọn kan sọ pe ka ba wọn fun ọkunrin naa ni pe ko ye e ri ara rẹ mọ, ko jẹ kawọn eeyan maa rii, ko si wa gbogbo ọna ti orukọ rẹ yoo fi pada bii ti tẹlẹ, bẹẹ lawa naa n gba a ladura pe orukọ Wale Dada ko nii wọlẹ loju aye rẹ lagbara Ọlọrun.
No comments:
Post a Comment