Ẹ FURA O, WỌN TI N FORUKỌ IJỌBA IPINLẸ OGUN LU AWỌN EEYAN NI JIBITI O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, July 6, 2019

Ẹ FURA O, WỌN TI N FORUKỌ IJỌBA IPINLẸ OGUN LU AWỌN EEYAN NI JIBITI O

Ọpọ awọn ti wọn gbọ pe ijọba ipinlẹ Ogun ti gbe ayelujara kan dide nibi ti wọn ti ni ki wọn maa forukọ silẹ fun iṣẹ ni wọn ti lọ n forukọ wọn silẹ, ṣugbọn to jẹ pe awọn oni jibiti ni wọn wa nidi ayelujara naa.

Gomina Dapọ Abiọdun ti gba ori ikanni ayelujara rẹ lọ lati kede sita pe ikanni ayelujara naa, http://jobs.ogunstate.gov.ng kii ṣe tijọba ipinlẹ Ogun, ati pe oun ko tii bẹrẹ eto igbanisiṣẹ, bo tilẹ jẹ pe awọn ti n gbe igbesẹ lati bẹrẹ.

AWIKONKO gbọ pe pupọ awọn laimọkan ni wọn ti bẹrẹ sii forukọ silẹ lori ikanni naa lai ṣewadii kikun lati mọ boya otitọ ni.

Bi ijọba yoo ba bẹrẹ igbanisiṣẹ, wọn yoo ti bẹrẹ ikede rẹ lori tẹlifiṣan ati redio, tawọn oniroyin naa yoo si ti gbe e jade sita. 

Ẹ fura o.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI