Beeyan ba ri bi gbajugba olorin takasufe nni, Kizz Daniel ṣe n binu kaakiri bayii pe iwe iroyin kan to gbajumọ daadaa lorilẹ-ede Naijiria, iyẹn Vanguard gbe iroyin kan jade sita lati fi ba oun lorukọ jẹ, to si jẹ pe awọn eeyan ti bẹrẹ sii bu ẹnu atẹ lu oun lori iroyin naa.
Kizz Daniel ninu ẹsun to fi kan iwe iroyin naa nile ẹjọ lo ti sọ pe wọn gbe iroyin kan jade lọsẹ to kọja pe oun sọ pe ori awọn gbajumọ oṣere ati olorin ti wọn n fẹsun kan Pasitọ ti wọn loo fipa ba ẹnikan sun, iyẹn Pasitọ Biọdun Fatoyinbo, eyi to n ja rain-rain lati bi ọsẹ meloo kan sẹyin ko pe.
Kizz Daniel loun ko sọ bẹẹ, ati pe ko si oniroyin kan to ba oun sọrọ lori nnkan naa, to si jẹ pe ikọkukọ ni wọn kọ nipa oun, eyi to sọ pe awọn ẹlẹgbẹ oun ti n bu oun lori iroyin naa.
Ni bayii, gbajugbaja olorin naa sọ pe oun n fẹ ki iwe iroyin naa tun iroyin naa kọ, ki wọn si bẹ oun ninu iwe iroyin wọn, ati pe wọn gbọdọ san owo ti ko din ni ọgọrun miliọnu naira foun gẹgẹ bi owo itanran ti wọn fi ba oun lorukọ jẹ.
No comments:
Post a Comment