Gbajumọ sọrọ ori redio nni, Ọmọtunde Adebọwale tọpọ awọn ololufẹ ẹ tun mọ si Lọọlọ ti jẹ ko di mimọ pe kii ṣe ẹbi oun pe oun n dalemoṣu, toun si tun jẹ iya n da gbe, ṣugbọn ti ko si nnkan toun fẹ ẹ ṣe sii.
Lọọlọ tawọn to tun mọ ninu gbajugbaja sinima ọlọsẹ-ọsẹ nni, iyẹn Jẹnifa tun mọ si Adaku lo sọrọ naa lasiko to n tu pẹẹrẹ-pẹẹrẹ ọrọ fun ileeṣẹ iroyin BBCYORUBA lonii nibi ifọrọwerọ ti wọn ṣe fun un.
Obinrin naa sọ pe ki i ṣe gbogbo dalemoṣu lo n ṣe aṣẹwo, bo tilẹ jẹ pe awọn kan n ṣe e, ṣugbọn iyẹn ko sọ pe koun ṣe e, tori iṣẹ toun yan laayo ko faaye gba iru iwa bẹẹ.
Ọmọ bibi ipinlẹ Ogun naa tun sọrọ lori ikọra-ẹni-silẹ, to si sọ pe ẹnu araye l'ẹbọ ninu ọrọ igbeyawo, nitori ohun ti wọn ma sọ ni pe ki lo de too ṣe sọrọ sita tabi o kuku ti n sọrọ ju.
Oṣere yii royin oun ti oju obinrin to ti kọ ọkọ silẹ
n ri lawujọ Yoruba.
Bẹẹ lo sọ pe boun ṣe n dalemoṣu ti n di nnkan itiju foun, nitori pe pupọ ninu awọn ọrẹ oun lawọn ọkọ wọn ti n le lọdọ oun, pe ki wọn yẹra foun tori pe oun ko si nile ọkọ.
O ni ki i ṣe nnkan to wu oun ni boun ṣe n dalemoṣu, ati pe ko si ẹni to wu lati dalemoṣu nile aye yi.
Adaku ni awọn eeyan maa n sọ pe awọn ọmọ obinrin ti
ko si nile ọkọ ko le yanju, ṣugbọn Olorun ju ẹda lọ.
No comments:
Post a Comment