BABA ARUGBO FIPA FA IDI ỌMỌDUN MẸRINLA YA NINU ILE AKỌKU L'EKOO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 8, 2019

BABA ARUGBO FIPA FA IDI ỌMỌDUN MẸRINLA YA NINU ILE AKỌKU L'EKOO

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti tẹ baba agba radarada kan ti wọn loo fipa ba ọmọdebinrin ẹni ọdun mẹrinla kan sun ninu ile akọku kan l'Ekoo.

Bo tilẹ jẹ pe titi dasiko ti a kọ iroyin yi tan ni Baba naa, ti wọn pe orukọ rẹ ni Aliyu Ali Mohammed ṣi n bẹbẹ pe ki wọn ṣe oun jẹjẹ, tori pe iṣẹ eṣu ni, ati pe lẹyin toun ṣe e tan loju oun ṣẹṣẹ la, sibẹ ohun tawọn kan n sọ ni pe ki wọn jẹ ki baba naa lọ ọ lo eyitoku aye rẹ lọgba ẹwọn.

Peace Estate to wa niluu Ekoo la gbọ pe Aliyu fipa wọ ọmọdebinrin naa ta a forukọ bo laṣiri wọ, to si fipa bọ pata ẹ, ko too bẹrẹ sii ko ibasun fun un karakara, ta a si tun gbọ pe ṣe lo fi aṣọ di ọmọ naa lẹnu lasiko naa.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun wa, agbẹnusọ fawọn ọlọpaa ipinlẹ Ekoo, Bala Ẹlkana sọ pe ọkan lara awọn to mọ nipa iṣẹlẹ naa, Harrison Chukwereuke lo fọrọ naa to ileeṣẹ wọn to wa ni Iba leti lọjọ keji oṣu yi, tawọn si rii pe loootọ ni lẹyin ọpọlọpọ iwadii.

O wa jẹ ko di mimọ pe Baba agbaaya naa ko ni pẹ ẹ foju bale ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI