Gbogbo awọn ọmọ onílẹ tó wà nílùú Ọ̀tà pátápátá tí fi ọkàn Aarẹ tẹlẹri lorilẹ-ede yi, iyẹn Oloye Oluṣẹgun Okikiọla Ọbasanjọ balẹ pé kò sí nnkan ti yoo ṣe àwọn ilẹ̀ rẹ tó wà lágbègbè Itele, níjóba ìbílẹ̀ Ado-Odò Ọ̀tà, ipinle Ogun.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn lawọn kan ti wọn ko mọ itan ni wọn lọ sori ilẹ Oloye Ọbasanjọ to wa lagbegbe Itele, nijọba ibilẹ Ado-Odo Ọta, ipinlẹ Ogun, ti wọn si fẹẹ sọ di ti wọn, ṣugbọn ti iroyin naa kan Aarẹ tẹlẹri lọwọ.
Wọn ni Ọbasanjọ ṣe gbọ nipa nnkan to ṣẹlẹ yi lo ti ranṣẹ si wọn ninu iluu naa pe bi wọn ko ba fẹẹ fi ẹnu fẹra bi abẹbẹ, afi ki wọn jinna rere kuro lori ilẹ oun, tori pe o ti pẹ toun ti ra ilẹ sibẹ, ti gbogbo ẹ si ni iwe ẹri.
Eyi ni eyi lo mu kawọn agbaagba agbegbe naa pe ara wọn jọ lati ṣewadi, ti wọn si rii daju pe otitọ ni, ti wọn si kilọ fawọn to wa nidi iwa ibajẹ naa pe ki wọn ma ṣe dawọ le nnkan ti agbara wọn ko nii ka, ati pe wọn ko gbọdọ ko awọn sinu wahala.
Lopin ọsẹ to kọja yi la gbọ pe awọn agbaagba agbegbe naa tẹkọ leti gba ile Aarẹ tẹlẹri naa lọ lati lọ fi to o leti, ti wọn si n fi i lọkan balẹ pe ko si nnkan ti yoo ṣe awọn ilẹ rẹ to wa niluu Itele ati agbegbe ẹ tori pe aabo ti wa nibẹ daadaa bayii.
Ko da, ti a tun gbọ pe wọn kọ atẹjade lati fi da Baba naa loju pe awọn mọ nnkan tawọn n sọ, ti kii sii ṣe ọrọ ẹnu rara. Ninu lẹta naa ni wọn ti sọ pe itan fidi ẹ mulẹ gẹgẹ bawọn baba wọn ṣe ti pitan fun wọn pe Oloye Ọbasanjọ ni ọpọ ilẹ niluu Itele.
Nigba to n sọrọ ninu lẹta naa, Ọgbẹni M. A Ọkandeji to duro gẹgẹ bi agbẹnusọ fun Oloye Taorid Dada to jẹ olori ẹbi Akapo Dada nilẹ Itele lo ti dupẹ lọwọ Oloye Ọbasanjọ fun ipa ati akitiyan ẹ lati mu idagbasoke ati ilọsiwaju ba agbegbe wọn.
Wọn jẹ ko di mimọ pe inu awọn dun lati rii pe Oloye Ọbasanjọ to tun jẹ Balogun gbogbo ilu Owu lorilẹ-ede Naijiria jẹ ọkan lara wọn, taọn si fi tayọ-tayọ gba lati di ọmọ ilu wọn.
Ọbasanjọ nigba to n gba ẹnu Oloye Abraham Idowu Akanle sọrọ dupẹ lọwọ awọn mọlẹbi to ba a lalejo naa, to si fi da wọn loju pe ajọṣepọ to dan mọnran ni yoo maa wa laarin wọn titi lai.
No comments:
Post a Comment