AWỌN MINISITA ATAWỌN AṢOFIN LO JẸ GBESE JU LORILẸEDE NAIJRIA - KURU PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, July 25, 2019

AWỌN MINISITA ATAWỌN AṢOFIN LO JẸ GBESE JU LORILẸEDE NAIJRIA - KURU PARIWO SITA

Ọga agba ati apaṣẹ ileeṣẹ to n ri sọrọ yiyẹ ile ati ileeṣẹ wo, iyẹn Asset Management Corporation of Nigeria, Ahmed Kuru ti sọ pe awọn minisita atawọn aṣofin lorilẹede Naijiria lawọn to jẹ ileeṣẹ naa lowo to pọju ninu tiriliọnu marun (5t) naira.

Bẹẹ lo sọ pe ileeṣẹ awọn tun n ṣiṣẹ papọ pẹluu ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu, iyẹn EFCC ati ICPC to fi mọ ileeṣẹ Nigeria Deposit Insurance Corporation lati le jẹ ki otitọ foju han gedegbe fawọn araalu.

Kuru to jẹ gẹgẹ bi oludanilẹkọọ ti eto ipade ounjẹ aarọ, eyi ti Nigerian – American Chamber of Commerce ṣagbekalẹ ẹ lo tu pẹẹrẹ-pẹẹrẹ ọrọ naa, to si ni oun ni lati jẹ kawọn eeyan, ti yoo si wa ni akọsilẹ fawọn iran to n bọ lọjọ iwaju pe iṣoro gbese owo tawọn n koju lati bi ọdun meloo kan sẹyin bayii ko ṣẹyin awọn oloṣelu lorilẹede yi.

Kuru jẹ ko di mimọ pe ọrọ naa n kan ileeṣẹ wọn lominu pupọ, to si tun jẹ pe pẹluu bi wọn ṣe n jẹ gbese to, awọn eeyan naa ṣi tun n ri aaye lati di ipo oṣelu kaakiri orilẹede yi, to si yẹ ki wọn wa atunṣe si.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe:

Si ibanujẹ, iru awọn eeyan nla ati ọtọkulu yi la n bọwọ fun ju lorilẹede Naijiria, ṣugbọn ti wọn ko si yẹ fun awokọṣe rara. Bawo ni wọn yoo ṣe jẹ awokọṣe nigba ti wọn ko le bọwọ fun ilana? Eyi lo fa a, ti mo fi n tẹnumọ ọn pe ki wọn da ofin banki (bank Act) pada. Bi a ṣe n mu ọrọ lorilẹede yi n jẹ eyi to n mu koriya fun awọn ajigbese. A ni lati maa jẹ kawọn eeyan jiya ẹṣẹ wọn, eyi ti yoo kọ awọn yooku lọgbọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI