AWỌN FULANI KII ṢE ỌMỌ ORILẸEDE NAIJIRIA, ERONGBA WỌN NI LATI GBA NAIJIRIA MỌ WA LỌWỌ – OYEBỌDE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, July 28, 2019

AWỌN FULANI KII ṢE ỌMỌ ORILẸEDE NAIJIRIA, ERONGBA WỌN NI LATI GBA NAIJIRIA MỌ WA LỌWỌ – OYEBỌDE

Gbajugbaja Ọjọgbọn ninu ofin nni, Ọjọgbọn Akin Oyedbọde ti jẹ ko di mimọ pe awọn ẹya Fulani ti wọn n da wahala silẹ lorilẹede yi ki ṣe ọmọ Naijiria rara, wọn kan fẹẹ fi tipatipa jẹ gaba le gbogbo awọn ọmọ oniluu lori ni.

Ọjọgbọn Oyebọde lo tu pẹẹrẹ-pẹẹrẹ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹluu akọroyin kan laipẹ yi, nibi to ti sọrọ lori eto aabo orilẹede yi nipa eto aabo, paapaa awọn ipalara ọjọ iwaju ilẹ Afrika.

Ọmọ bibi ipinlẹ Ekiti naa sọ pe bi wọn ba n gbiyanju lati tan awọn ọmọ orilẹede yi jẹ, awọn ni wọn ko gbọdọ lati jẹ ki ẹnikẹni fi nnkan bo wọn loju nitori pe itan ati arọba, pẹluu ọrọ tawọn to sunmọ ẹya Fulani n sọ lẹnu ni pe wọn kii ṣe ọmọ orilẹde yi, ati pe wọn ko ni ibi ti wọn le pe ni ilu ara wọn, bi ko ṣe pe ki wọn jagun lati gba ilu onilu.

Ninu ọrọ rẹ, Ọjọgbọn naa sọ pe “Aarẹ ti figba kan ri sọ pe awọn Fulani ti wọn pawọn eeyan kaakiri ki i ṣe ọmọ orilẹede Naijiria, bi ko ṣe pe awọn orilẹede bii Libya, tawọn kan si sọ pe awọn alagbara kan ti wọn kii ṣe ọmọ orilẹede yi ni wọn wa lẹyin bi eto aabo orilẹede yi ṣe mẹhẹ, pẹluu ofin ajọ ECOWAS to faaye gba awọn to wa labẹ ẹ lati rin pẹluu alaafia kaakiri, ṣe awa le di ẹbi le ofin ati ilana naa bi, abi ka fi ṣe awawi lasan?


Emi ko le gba ẹnu Aarẹ Muhammadu Buhari sọrọ, nitori pe o ni ẹkunrẹrẹ nnkan to n ṣẹlẹ ju mi lọ, ṣugbọn mo mọ pe orilẹede Chad ati Cameroon ko si labẹ ajọ ECOWAS, nitori naa bi wọn ba sọ pe awọn ibomin in lawọn Fulani ti n wa, wọn ni lati fi oju ṣunnukun wo o daadaa. Ni temi o, Buhari fẹ ẹ maa lo agabagebe lati bu ẹnu atẹ lu awọn awọn ti wọn fẹ ẹ jẹ gaba yi, to si jẹ pe awawi lasan lo n wa lati maa da awọn eeyan ti wọn fẹẹ jẹ gaba le wa lori naa lare.

Ẹ jẹ ki n sọ ipilẹ wọn fun un yin, Futa Jallon, Senegal, Mali ati apa kan ni Guinea lawọn Fulani ti ṣẹ wa a. Ko da a, Usman dan Fodio to jẹ olori wọn agba ki i ṣe ọmọ Naijiria. Awọn Fulani ko ni ipinlẹ kankan tabi itẹdo lorilẹede Naijiria. Ṣe ni wọn ya wọ ilẹ Hausa, ti wọn si gba gbogbo ẹ mọ wọn lọwọ lọdun bii meloo kan sẹyin, ti wọn si tun sọ ara wọn di Ẹmir le wọn lori.

Usman dan Fodio funra rẹ sọ pe oun ni lati wa a tọwọ bọ Quran ni Atlantic, ṣugbọn awọn Yoruba ni lati da a duro niluu Oṣogbo. Ẹ mọ itan Afọnja niluu Ilọrin, atawọn apa kan ni Ariwa ilẹ Yoruba abi awọn agbegbe bii Ikar ati Auchi, nibi ti wọn tun ti fẹ ẹ yan Ẹmir ni tipa-tipa.

Ninu wọn gan an tun n sọ pe Ọlọrun lo fi aami ororo le Naijiria lọwọ lati jẹ ti wọn, awọn si ni ominira lati agbegbe ti wọn ti wa lati ja gba nnkan to jẹ ti wọn. To ba jẹ lati gba Naijiria ni ipinu ti wọn lawọn ni, sibẹ wọn ko le sọ pe gbogbo awọn to wa nibẹ nii ki i ṣe ọmọ onilu. Gẹgẹ bi a ti maa n sọ nipinlẹ Ekiti ti mo ti wa pe ‘onikaluku lo mọ ile baba rẹ’, bi wọn ko ba ti le juwe ile baba wọn, wọn a ṣi maa wa awọn ibi ti wọn fẹ ẹ gba ni tipatia ṣaa ni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI