Orin 'tun mi gbe, ọkọ mi tun mi yan' ni wọn n kan fun iya arugbo, ẹni ọdun mẹtalelọgọta kan nipinlẹ Zaria lai pẹ yi pẹlu boun ati ololufẹ rẹ ṣe ṣe igbeyawo alarinrin.
Kaakiri ori ayelujara lawọn to gbọ si ohun to ṣẹlẹ ti n fi ṣe ọrọ sọ, ti wọn si n sọ pe ko si'gba ta a daṣọ, ti a ko rẹni wọ ọ, ati pe ko si nnkan ti ko le ṣẹlẹ labẹ ọrun ti a wa yii.
Ẹnikan ti wọn pe ni Chinecherem Ebubechi lo gbe fọto awọn ololufẹ meji naa sori ikanni ayelujara ti Facebook, pe baba agbalagba ẹni ọdun mẹtalelaadọrin (73) kan, Matthew Owojaiye ti wọn tun sọ pe Ajihinrere ni lo gbe mama agbalagba naa Abọsẹde Ayọbọla niyawo.
Ohun to n jẹ kayeefi, to mu kawọn eeyan maa sọrọ lori igbeyawo naa ni bi wọn 'se sọ pe ni nnkan bi aadọta ọdun sẹyin ni Baba naa ti kẹnu ifẹ si mama yi, ṣugbọn to sọ pe oun ko ṣe, ṣugbọn nigba tawọn mejeeji tun maa pade ara wọn, iyalẹnu lo jẹ pe awọn mejeeji ko tii ni ololufẹ.
Eyi lo jẹ ki mama yi tun pada gba lati fẹ ẹni to ti kẹnu ifẹ sii lati ọpọlọpọ ọdun sẹyin.
Ṣọọṣi Baba Oyedepo, iyẹn Living
Faith to wa nipinlẹ Zaria ni wọn ti ṣegbeyawo naa pẹluu mọlẹbi, ọrẹ atawọn abaniyọ wọn.
No comments:
Post a Comment