Pupọ awọn to ri mọto ti gbajugbaja oṣere adẹrinpoṣonu nni, Ayọdeji Richard Mayọkun ṣẹṣẹ ra laipẹ yi lo n ṣe ni kayeefi, to si mu kawọn kan maa sọ pe kii ṣoju lasan mọ, tawọn min in si n sọ pe ko si nnkan to buru nibẹ.
Ọmọ bibi ilu Ifọn nijọba ibilẹ Ose, ipinlẹ Ondo naa lo gbe fọto ara rẹ ati mọto naa sori ikanni ayelujara rẹ, to si ni kawọn eeyan ba oun dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ẹbun tuntun Lexus LX570.
Ayọdeji tọpọ awọn eeyan tun mọ si A.Y Makun sọ pe oogun oju oun loun fi ra mọto ra a.
Bẹẹ lawọn kan n fi mọto naa gbadura pe ki Ọlọrun pese ẹbun awoṣifila naa ta awọn lọrẹ.
No comments:
Post a Comment