ÀLỌ́ ONÍTÀN: ÌJÀPÁ TỌ̀HUN TI IKARAHUN Ẹ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 8, 2019

ÀLỌ́ ONÍTÀN: ÌJÀPÁ TỌ̀HUN TI IKARAHUN Ẹ̀

Á: À-à-lọ́-ọ

B: À-à-lọ́

Á: Àló mi dá fììrìrì gbàá-gbòó.

B: Kó má gbágbo ọmọ mi lọ.

Àló mi dálé lórí ìjàpá ológbón ẹ̀wé pèlú ìkarahun è.

Lójó tí o sojú ojó kó, tó tutù bí ààjìn t'éwé sí n fé lele lele, ìjàpá n ré kọjá lójúnà ọjà.

Sè gbogbo wa la s'àkíyẹ̀sí  pé ìjàpá féràn láti máà kétí. Nisè ni ó gbó pé àtíoro àti ikún n sòrò ohun. Ní kíákíá ni o rápálá wo abé tábílì tí wọ́n n gbé tajà.

Atíoro ló n sòrò lówó, ó ní: Nkàn ti è lè fira mi sípò tí ìjàpá wà, kí máà rábábà nilẹ̀ pẹlú kinikan kantẹ léyìn bí igbá tí wọ́n n pè ni ìkarahun. Oorun ayérayé ni kinní ọ̀hún o fàá pẹ̀lú àhámọ́ nla.

Ikún ní : Mamà dá aláwàdà rẹ̀ lóhùn. Bó sẹ̀mi ni Elédùà fi irú è dálólá, máà ti yọ kúrò nínú rẹ̀ tipátipá. Kí atégùn rere róhun fèsì olúwarè léyìn.

Ìjàpá fetí sí  Gbogbo ọrọ náà láì kùkan. Ó pakítí móra kò fohùn torí kí o le baà rímíi gbóo.
O dúró kí ojú ojó pofíri diẹ kí o tó kọjá sibí tí ọ́ n lo. Sèbí ó kúkú n rí èpà tí n daale lówó àṣàkẹ́ elépà je.

Nígbà tí ìjàpá dé sílé láti ibi tí o lọ, o sùn sórí ìbùsùn, gbogbo òrò tí o fetí kó lénu àtíoro àti ikún.

O pinu láti tún ara rè dáa, o ṣètò bí yóò ṣe yọ kúrò nínú awo rè. Ìkarahun rè tí o má n fí yogàn láwùjọ d'ohun tí o sadeede kórira. Kọ̀ba yo kúrò nínú awo náà ní wàrà n sesà sùgbọ́n ó ti rìn jù lójó náà.

Ìpàdé di ìgbà tí ilè bá mó. Bí oyè se la, tí ilè mó, o bèrè isé àtúndá náà. O fosoke, o juwo le. O gbìyànjú Títí to fi di pe o un yóò díèdíẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó se féé. Nígbà tí yóò di dalé, arákùnrin náà ti di àtúndá, o ti kù gborongidi bí oba-òkè kò se ṣ'èdá e.

Inú rè dùn gidigidi nínú ìnira náà, o ní òhun n lo ki atíoro lẹyìn náà ikún. Ó ku kórìn, kòrìn dáadáa, o sòpá s'ílékùn, ó sáré wọlé padà nítorí òtútù..

Odaa náà, òhun yóò lọ ní àárò kùtùkùtù òwúrò òla. Kó sùn lórí ìbùsùn, kòrí oorun sùn, béèni òtútù n muu. Òtútù yìí lórán ìjàpá l'órun aremabo. Ó tóo bí ojó keta kí àwọn ará àdúgbò tóo mòpé ó tí ta téru n pa.

Èyí ní fún gbogbo òdó ìwòyí tó n sáré bí yóò ṣe bó lówó àwọn òbí rè, o gbagbe pé a kìí yóò ounjẹ alé eni je.

Àgbàlagbà niyin, dádì wa, awọn mọ̀lébí n pariwo kí é kúrò nínú ìwà ìbàjé yín, è n warùnki. È gbagbe pé aṣọ ara ẹni kò ṣeé yo dànù.

Bí a bá sí omorí igbá a tabuku igbá, bí a yóò ìlà inú tiró a di ohun tí kò wùlò fáráyé. Bí kèrèwú bá kúrò nínú egungun, á á rún jégéjégé.

E jé kí a sóra kí a máa bá yóò kúrò nínú ikarahun wa, iparun nla nì o máa n fàá. Ire kàbìtì.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI