AGBẸJỌRO TO KERE JULỌ NILẸ ALAWỌ DUDU RE O, ỌMỌ IPINLẸ EKITI NI WỌN PE E - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, July 16, 2019

AGBẸJỌRO TO KERE JULỌ NILẸ ALAWỌ DUDU RE O, ỌMỌ IPINLẸ EKITI NI WỌN PE E

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, ọdọmọbinrin ti ẹ n wo yi ni agbẹjọro to kere julọ ninu itan ilẹ alawọ dudu, iyẹn Afrika, to si tun jẹ ekeji ni gbogbo agbaye ninu itan.

Oluwagbemileke Joy Jẹgẹdẹ ni wọn pe orukọ ẹ, to si jẹ pe ọmọ ogun ọdun pere ni. Ọjọ kinni in, oṣu kẹta ọdun 1998 ni wọn bi Joy Jẹgẹdẹ ti wọn lọmọ bibi Ọyẹ Ekiti, nipinlẹ Ekiti ti Dọkitọ Kayọde Fayẹmi jẹ Gomina wọn.

 
AWIKONKO gbọ pe ọmọdun mẹsan ni Joy wa to ti kẹkọọ jade nileẹkọ alakọbẹrẹ, to si tun yege ninu idanwo akanṣe ti Basic Education School Exams nigba to wa lọmọdun mejila.

Iyalẹnu ni wọn loo jẹ nigba ti awọn ile ẹkọ fasiti meji n lee mu kaakiri pe awọn fẹ ẹ gba sọdọ wọn lẹyin to yege daradara ninu idanwo aṣekagba tile ẹkọ girama, iyẹn WAEC ni kete to pe ọmọdun mẹrinla.

 
O tun jẹ nnkan iyalẹnu nigba ti Joy tun yege nigba to wa lọmọdun mẹtadinlogun, to si gba iwe ẹri '1st Division in Bachelors of Administration', bẹẹ lo tun gba 'First Class Honours in Law' ni kete to pe ọmọdun mejidinlogun, iyẹn nileewe Fourah Bay College to wa ni orilẹede Sierra Leone.

Ọmọ ogun ọdun ni Joy di agbẹjọro, to si jẹ pe ninu itan ilẹ Afrika, Joy lo kere julọ, to si jẹ pe oun lẹnikeji to kere julọ ninu itan agbaye.

 
Pasitọ ni wọn pe Baba ati Mama Joy, Pasitọ Oluṣọla ati Olubunmi Jẹgẹdẹ, ti wọn fi orilẹede Sierra Leone ṣebugbe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI