Ko sẹni ti yoo ri fọto gbajugbaja agba oṣere tiata nni, Alagba Toyọsi Arigbabuwo lori kẹkẹ awọn arọ, ti aanu abiyamọ ko ni i ṣe e, pẹlu bi wọn ṣe ni aisan kan dee de kọlu.
Digba-digba la gbọ pe wọn sare gbe ọkunrin naa lọ sile iwosan UCh to wa niluu Ibadan laipẹ yi nigba ti wọn lọrọ naa fẹẹ yiwọ mọ wọn lọwọ.
AWIKONKO gbọ pe obitibiti owo lawọn mọlẹbi agba oṣere naa ti na lee lori, ti ko si dabi pe wọn na owo kankan.
Fawọn to ba n wo sinima daadaa, wọn a mọ pe o ti ṣe diẹ ti Alagba Arigbabuwo ti kopa ninu fiimu gbẹyin, ko si si nnkan meji, bi ko ṣe ti aisan ti wọn lo n daamu ẹ yi.
Ki Ọlọrun ba wa fun un ni alaafia.
No comments:
Post a Comment