Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta
Ara ko rokun, bẹẹ ni ara ko ni i rọ adiyẹ ni wọn lawọn araalu Ọpẹlifa to wa ni Ọbada, Abẹokuta fọrọ naa ṣe lọjọ
Fraide ọsẹ to kọja yii nigba ti wọn sọ pe Alake fẹẹ gbiyanju lati gbe ade le
ọkunrin kan ti wọn pe ni Kaṣimawo Adisa Ogundele, ẹni ti wọn ni ki i ṣe ọmọ ilu
naa lori.
Ohun ta a gbọ ni pe ọmọ bibi
ilu Awori nijọba ibilẹ Ipokia ni wọn sọ pe awọn baba-nla Ogundele ti wa a ra
ilẹ siluu Ọpẹlifa, ko too di pe wọn bẹrẹ si i pọ niluu naa, ṣugbọn tawọn ọmọ
ilu naa fi ifẹ gba wọn mọra.
Nibi ti wọn sọ pe wọn f'ifẹ naa han de, lo mu ki wọn ṣagbatẹru Kaṣimawo Adisa Ogundele lati di kansẹlọ lasiko
Gomina ijẹta, Ọtunba Gbenga Daniel, ti wọn si sọ pe ibi lo fi ṣu wọn lasiko
naa.
Oloye Awopeju Saheed |
AWIKONKO gbọ pe ni nnkan bi
ọdun kan aabọ sẹyin ni wọn fi Oloye Awopeju Saheed Olumide jẹ Baalẹ ilu
Ọpẹlifa, ti gbogbo ilu si fọwọ sii, ko da, ti wọn sọ pe Alake ilẹ Ẹgba, Ọba
Gbadebọ lo gbe ọpa aṣẹ ati iwe ẹri fun ọkunrin naa nigba naa.
Ṣadede ni wọn sọ pe Gomina ana
nipinlẹ Ogun, Sẹnetọ Ibikunle Amosun fawọn Ọba kan jẹ, ti wọn si l’ayederu ni pupọ
ninu awọn Ọba yii, ati pe ẹmi imọ-oore ni Amosun fi han sawọn to fi jọba naa,
eyi ti wọn ni Kaṣimawo Ogundele naa wa lara wọn.
A ti ẹ gbọ pe ọkan lara awọn
oloye ẹgbẹ oṣelu APM ni Kaṣimawo Ogundele, ati pe iṣẹ takuntakun to ṣe lasiko
idibo apapọ ati Gomina to kọja yi lo mu ki Gomina Amosun sọ ọ di ọba, ti wọn si
fọwọ gba Baalẹ ilu naa sẹyin.
Ohun to n jẹ kayeefi ni ba a sẹ
gbọ pe ori redio lawọn araalu ti gbo iroyin pe ọkunrin naa ti di ọba, nitori ti
wọn sọ pe ko si afọbajẹ kankan, paapaa awọn araalu to mọ si.
Ọjọ Fraide to kọja yi ni wọn sọ
pe Alake tilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ f'ipade si pe ki gbogbo awọn ọba
marundinlọgbọn ti Gomina ana yàn, ìyẹn tó wà lábẹ́ Aláké wa a gba ade wọn, eyi ni wọn loo mu kawọn ọmọ
bibi ilu naa gbe ifẹhonu han lọọ si Aafin Alake lati ma ṣe jẹ ki eto naa waye.
Nigba to n sọrọ pẹlu ibanujẹ
ọkan, Oloye Awopeju Saheed Olumide to jẹ Baalẹ Ọpẹlifa so pe “Iyalẹnu lo jẹ pe
Gomina ana, Ibikunle Amosun le da wahala nla silẹ ko too kuro nipo, tori pe oun
lo f'awọn kan ti wọn kì i ṣe ọmọ ilu wa j’ọba le wa lori, ilu Awori lawọn
baba-nla wọn ti wa gbe lọdọ wa, ko too di pe a ta ilẹ fun wọn.
“Ẹhọnu la wa fi han pe wọn ko
le gbe ade le ẹni ti ki i ṣe ọmọ ilu lori, kò sì lè j’ọba le wa lori, tori pe Baalẹ wa niluu,
ati pe gẹgẹ bi iwe ofin ṣe fi ye wa, Baalẹ ni wọn n sọ di ọba ilu. Lootọ, o ti
jẹ kansẹlọ ri lasiko Ọtunba Gbenga Daniel, to si tun ṣiṣẹ fun ẹgbẹ oṣelu APM
ninu idibo to kọja yi.
“Ko sẹni to mọ igba ti Gomina
mú u gẹgẹ bi ọba, ori redio la ti n gbọ pe wọn fi jẹ ọba, ko si afọbajẹ kankan
to gbọ nípa ẹ, to fi mọ awọn araalu, oku oru ni wọn fi ṣe, oniluu ko si ni i la
oju ẹ sile, ko jẹ ko tu mọ oun lori.
“Olu-Ọbada mọ nnkan to n ṣẹlẹ
to si ti gba wa lamọnran, bẹẹ la tun ti fọrọ naa to Alake tilẹ Ẹgba leti,
ṣugbọn ti wọn ko ti i gbe igbesẹ kankan nípa ẹ, iyalẹnu lo jẹ pe Alake ti gbe ade
le ọkunrin naa lori. Ayederu ọba ni wọn fi jẹ. Mo si n fi asiko yii bẹ Gomina
tuntun, Dapọ Abiọdun pe ko tete ba wa da si ọrọ yii, tori pe o ṣee ṣe kọrọ naa
da ogun silẹ niluu wa.”
Olu tiluu Ọbada, Ọba Oluwafẹmi Abiọdun
Ṣolaja, Afẹjanlajiyan nigba to n b’AWIKONKO sọrọ ni “Mo gbọ si nnkan to n
ṣẹlẹ naa, ati pe Baalẹ wa niluu Ọpẹlifa to si jẹ ọmọ bibi ilu naa gangan, emi
ni mo fi baalẹ naa jẹ, ti Alake ilẹ Ẹgba naa si fọwọ si i. Ko da, gbogbo Ilu
Igbein naa fọwọ si i.
“Oṣelu ẹtanu loun to ṣẹlẹ yi,
nnkan ti Gomina Amosun ṣe ko too lọ ku diẹ kaato nitori pe ọpọ awọn to lọ ba
a ko sọ nnkan to n ṣẹlẹ lagbegbe yẹn fun un, toun naa ko si ṣewadii. Ọba kí i pe
meji laafin. Awa ko le yẹ Gomina Amosun lọwọ wo, tori pe oun gbogbo lo ni igba
ati asiko.
“Asiko ti wọn n ṣe ti wọn,
agbara wa lọwọ wọn ni, eyi ti ko jẹ ka ṣe nkankan, ṣugbọn ni bayii ti wọn ti lo
agbara wọn tan, mo nigbagbọ pe gbogbo wahala naa ni Gomina tuntun Dapọ Abiọdun
yoo yanju.”
Gbogbo akitiyan lati ba Oloye
Layi Labọde (Baaroyin ilẹ Ẹgba), to jẹ agbẹnusọ fun Alake tilẹ Ẹgba sọrọ lo ja
si pabo, nigba ti baba naa kọ jalẹ lati sọrọ lè e lori. Bakan naa ni Kaṣhimawo
ti wọn pe l’ayederu ọba yi sa fun AWIKONKO lati sọrọ titi dasiko ta a kọ iroyin
yii tan.
No comments:
Post a Comment