WỌN LU FULANI TO N FIPA BAWỌN OBINRIN SUN PA L'ẸDO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, June 28, 2019

WỌN LU FULANI TO N FIPA BAWỌN OBINRIN SUN PA L'ẸDO

Beeyan ba wa nibi tawọn ọdọ kan tinu n bi ṣe lu ọkunrin kan ti wọn pe ni Fulani pa lọjọ Iṣẹgun to kọja yi, wọn ko nii kaanu ẹ rara, latari wọn ṣe sọ pe oun naa fipa ba obinrin kan sun, to si tun ṣa a pa.

Opopona Benin si Ọrẹ la gbọ pe iṣẹlẹ naa ti waye nigba ti wọn sọ pe awọn Fulani kan ti wọn maa n fojoojumọ dawọn eeyan lọwọ kọ, ti wọn si n fipa bawọn obinrin, paapaa awọn ọlọmọge laṣepọ, gbe iyaale ile kan wọnu igbo, ti wọn si baa sun karakara.

 
Ohun ta a gbọ ni pe ṣadede ni wọn ba oku obinrin naa ninu igbo, ti wọn si kofiri awọn Fulani kan ti wọn wa nidi iwa buruku naa, loju ẹsẹ la gbọ pe awọn ti wọn ri oku obinrin naa pariwo sita, ti wọn si le awọn Fulani naa wọgbo.

 
A gbọ pe ọwọ tẹ ọkan lara wọn, ti wọn si gbe e jade soju opopona lati luu, nibi ti wọn ti n luu ni wọn ti luu pa, ti wọn si pin ẹya ara rẹ si wẹwẹ lẹyin ti wọn pa a tan, ta a si tun gbọ pe wọn dana sun un

A ti ẹ gbọ pe awọn oloṣelu kan ti wọn n kọja lọ pẹluu ọkọ akọwọrin wọn, ṣugbọn ti wọn lawọn eeyan ko jẹ ki wọn kọja lasiko iṣẹlẹ naa, iyẹn lagbegbe Ọkada, nitosi Benin.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI