Bo tilẹ jẹ pe a ko ti i le fidi iṣẹlẹ naa mulẹ titi dasiko ta a kọ iroyin yi tan, ṣugbọn sibẹ, kayeefi niku Baalẹ agbegbe Vopba to wa nijọba ibilẹ Gokana, ipinlẹ Rivers, Oloye Menele Gberegbara ṣi n jẹ fawọn eeyan titi dasiko yi.
Ọjọ Sande ana la gbọ pe awọn kan ti wọn ko wọ aṣọ, ṣugbọn tawọn eeyan gbagbọ pe ọlọgun ni wọn yawọ agbegbe naa, ti wọn si da ibọn bolẹ.
Sẹ la gbọ pe awọn ara agbegbe naa ba ẹsẹ wọn sọrọ nigba ti wọn gburo ibọn, ṣugbọn nigba ti gbogbo nnkan lọ silẹ, ti wọn lawọn eeyan n jade sita pada ni ṣa dede ba oku Oloye Menele nilẹ, ti wọn ti fibọn ba ti ẹ jẹ.
Ohun ta a gbọ ni pe, iwadii ṣi n lọ lọwọ, to si mu kawọn eeyan maa beere lọwọ ara wọn pe ki lo le ṣẹlẹ.
No comments:
Post a Comment