WỌN LAWỌN KAN FẸẸ YẸYẸ IBIKUNLE AMOSUN NI YIDI, LOUN NAA BA KỌ LATI YỌJU - IROYIN AWIKONKO

Tuesday, June 4, 2019

demo-image

WỌN LAWỌN KAN FẸẸ YẸYẸ IBIKUNLE AMOSUN NI YIDI, LOUN NAA BA KỌ LATI YỌJU

Ibikunle+Amosun+%25283%2529
A fi bi i pe ẹni pe Gomina ana nipinlẹ Ogun, Sẹnetọ Ibikunle Amosun ti mọ pe awọn kan ti korajọ lati yẹyẹ oun ni Yidi to ti maa n kirun lọdọọdun lasiko ọdun Itunnu Aawẹ ati ti Ileya, iyẹn Yidi to wa ladugbo Oke-Yidi, Lanoro niluu Abẹokuta.

Fawọn to ba mọ bi nnkan ṣe n lọ nipinlẹ Ogun, paapaa lasiko oṣelu to ṣẹṣẹ kọja yi, wọn a mọ pe Ibikunle Amosun ko faramọ Gomina Dapọ Abiọdun tawọn ọmọ ipinlẹ naa dibo fun un, paapaa bo tun ṣe sọ lasiko ọdun to Itunnu Aawẹ ati Ileya to kọja pe oun ati Gomina toun ba fa kalẹ lawọn yoo jọ wa kirun ni Yidi lọdun yi.

AWIKONKO gbọ pe latigba Sẹnetọ Ibikunle Amosun ti gbe ijọba silẹ lọsẹ to kọja yi, lawọn eeyan ti n beere pe bawo lawọn ṣe fẹẹ ṣe ayẹyẹ ọdun yi, to si ṣeleri pe oun yoo ti de lati Umura toun n lọ lati wa a bawọn kirun ni Yidi naa.

Ireti awọn eeyan gẹgẹ ba a ṣe gbọ, paapaa awọn kan ti wọn ni wọn ti mura silẹ lati yẹyẹ Amosun ni Yidi naa lonii ni pe bo ba fi le wa sibẹ, awọn ko ni i bẹru ẹ lati sọ ọ kan loju pe ijọba adaṣe lo ṣe fun odindi ọdun mẹjọ to lo nipo.

Ko da, a gbọ pe wọn tun ti mura silẹ lati ju Gomina ti Amosun loun fẹẹ fa kalẹ, iyẹn Ọnọrebu Adekunle Akinlade lokuta ati omi inu ọra, iyẹn Pure Water bi wọn ba foju kan an ni Yidi.

Ṣugbọn ṣe la gbọ pe ọrọ naa yiwọ mọ wọn lọwọ, ti ko si ri bi wọn ṣe lero nigba ti wọn reti ọkunrin naa ati Ọnọrebu Akinlade titi di nnkan bi aago mọkanla, ti wọn ko ri i, to si jẹ orin 'Ọlọrun yọ' ni wọn n kọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI

Contact Form

Name

Email *

Message *