Bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọọ laipẹ yi ba fi le jẹ otitọ, a jẹ eto aabo orilẹ-ede Naijiria, paapaa ilẹ Yoruba ti mẹhẹ patapata, tijọba apapọ ko si tii ṣetan lati wa nnkan ṣe sii lori bawọn ajinigbe ṣe n fojoojumọ ṣọṣẹ kakiri.
Laarọ onii la tun gbọ pe awọn agbebọn kan dawọn eeyan duro loju ọna Akurẹ si Ikẹrẹ, ti wọn si wa gbogbo awọn to wa ninu mọto bọọsi wọnu igbo kijikiji, to fi mọ awakọ naa.
Iluu Ado-Ekiti la gbọ pe awọn ero inu Bọọsi naa n lọ lati Akurẹ, nigba ti wọn si maa de agbegbe kan ti opopona ko ti dara la gbọ pe awọn agbebọn yi ti dina mọ wọn, ti wọn si le gbogbo wọn bọ silẹ ninu mọto.
Titit di asiko ti a kọ iroyin yi tan la ko tii gbọ ibi ti wọn ko awọn eeyan naa lọ.
No comments:
Post a Comment