Diẹ lo ku ki gbajugbaja pasitọ kan to filuu Abuja ṣebugbe, Basil Princewill daku nile ẹjọ giga kan to fikalẹ sagbegbe Maitama lọjọ Tuside ana nigba ti Onidajọ Hussein Baba-Yusuf paṣẹ pe ko sare lọọ ṣe faaji ọdun meje pere lọgba ẹwọn lati jiya ẹṣẹ ti wọn fi kan an pe o fipa ba ọmọdebinrin ọmọdun mẹrinla kan lo pọ, to si tun fun un loyun.
Kii ṣe pe oyun ti Basil Princewill fun ọmọdebinrin naa lo jẹ ki wọn foju ẹ balẹ, bi ko ṣe pe o ti gbiyanju laimọye igba lati yọ oyun naa fun ọmọ yii, tọ wọn si lo tun dunkooko lati pa a danu bi ko ba fọwọsowọpọ pẹluu oun, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Ohun ta a gbọ ni pe Basil Princewill to jẹ olusailẹ ṣọọṣi Mountain Mover Ministry International to wa ni Nyanya, Abuja fipa ba ọmọ naa sun lẹẹmeji ọtọọtọ, iyẹn lọjọ
ẹtadinlọgbọn oṣu keje ati ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kejila ọdun 2011, ko too di pe o loyun.
Wọn ni bi Princewill ṣe rii pe ọmọ naa ti loyun lo ti bẹrẹ sii gbe igbesẹ lati fipa yọ oyun naa ki aṣiri ma baa tu, to si ti fun ọmọ naa loriṣiriṣi oogun ki oyun naa le jabọ, ṣugbọn ti aṣiri pada tu sita nigba ti ọmọ naa dubulẹ aisan.
Bo tilẹ jẹ pe ọpọ igba ti wọn ti foju Basil Princewill bale ẹjọ lo ti n bẹbẹ pe ki wọn foju aanu wo oun tori pe iṣẹ eṣu ni, toun ko si nii lero rara pe oun le ṣe iru nnkan bẹẹ.
Ṣugbọn Ọnidajọ naa sọ pe ko si nnkan toun le ṣe ju koun tẹle ofin ọdaran to lọ nibamu pẹluu ijiya, nitori naa, ko lọọ fi ọdun meje naa ronupiwada, ati pe nigba ti yoo ba fi jade, yoo ti gba ojulowo ẹmi mimọ ti yoo fi maa waasu fawọn ẹlẹṣẹ.
No comments:
Post a Comment