Ọla Eyitayọ, Ọyọ
Inu idaamu ni idile Ọjọgbọn
Isaac Adewọle, to jẹ minisita fọrọ eto ilera lorilẹ-ede Naijiria to ṣẹṣẹ gbe
ipo silẹ wa titi di asiko ti a ṣakojọpọ iroyin yi tan lori bawọn agbebọn kan ṣe
ji ọmọ ẹ, Dayọ Adewọle gbe nirọlẹ ana Tuside.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, agbegbe kan
ti wọn n pe ni Iroko, nitosi Fiditi to wa nijọba ibilẹ Afijio, ipinlẹ Ọyọ ni
wọn ti ji Dayọ gbe lasiko to n lọ sinu oko ẹ. Alukoro ilẹ-iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ
Ọyọ, Ọgbẹni Olugbenga Fadeyi lo fidi iroyin na mulẹ laarọ oni fawọn oniroyin,
to si ni igbesẹ ti n lọ lori bi wọn yoo ṣe ri Dayọ gba lọwọ awọn agbebọn naa.
A gbọ pe ni nnkan bi aago mẹfa
aabọ irọle ana tii ṣe Tuside ni wọn lawọn agbebọn mẹrin naa tọpinpin Dayọ de
agbegbe Iroko naa, ti wọn si gbe e lọ. Awọn ti wọn niṣẹlẹ naa ṣoju ni wọn tawọn
ọlọpaa Mọniya lolobo, ti wọn si ti gba tọ wọn loju ẹsẹ.
Olugbenga sọ pe awọn ti ko awọn
ọlọpaa kogberegbe sita lọpọ yanturu lati rii pe wọn ri awọn agbebọn naa mu, ati
pe awọn ti ri mọto ti wọn fi ji Dayọ gbe, tawọn si ti gbe e kuro nibi ti wọn ti
rii.
Nnkan to n ṣe awọn eeyan ni
kayeefi ni pe asiko ti Ọjọgbọn Adewọle ko si nile ni wọn ji Dayọ, ọmọ rẹ gbe,
ti wọn si ni wọn ti fọrọ naa to o leti, ati pe lẹsẹkẹsẹ lo ti lọọ wọ ọkọ
ofurufu lati maa pada bọ ni Naijiria.
Bẹẹ lo jẹ ko di mimọ pe awọn agbebọn naa ko tii pe
ẹnikẹni yala lati beere owo ni, tabi sọ pato nnkan ti wọn n fẹ.
No comments:
Post a Comment