Bo tilẹ jẹ pe latigba ti Ọba
Halidu Adedayọ Ọlaloko to jẹ Agura tiluu Gbagura ana ti waja lọjọ kẹtala oṣu
keje ọdun to kọja ni wahala tani yoo de ori ipo naa ti wa nilẹ, tawọn idile ti ọba kan ti bẹrẹ sii gbena woju ara wọn, ṣugbọn ṣe lọrọ tun bẹyin yọ lọsẹ to
kọja yi nigba tawọn idile mẹrin ọtọọtọ to wa labẹ Egiri gbe ijọba ipinlẹ Ogun, Ọba tuntun atawọn afọbajẹ to wa ni yara Ipebi lọ sile ẹjọ.
Ko si nnkan meji ti wọn loo fa
wahala to n ṣẹlẹ naa bi ko ṣe ohun ti wọn sọ pe Adajọ fẹyinti Demọla Bakre ti
wọn loo fipa fa ara rẹ silẹ gẹgẹ bi olori ẹbi Egiri ṣe sọ pe Ọmọba Saburee
Babajide Bakre loun fẹ ko di Ọba Agura tiluu Gbagura tuntun latari pe o jẹ ọmọ ẹgbọn ẹ, ti
wọn si lawọn araalu atawọn ti wọn jọ n du ipo ko faramọ.
AWIKONKO gbọ pe awọn ti ko
din ni mẹrinla ni wọn n du ipo naa tẹlẹ ki wọn too ku mẹsan an, ati pe diẹ lara wọn ni: Ọmọba Akinyẹle Ṣarafadeen Ogunwọọlu ti idile Ijaade; Ọmọba Taofeek Adebayọ Ajani ti idile
Jamolu; Ọmọba Saburi Ayinde Adeyẹmi ti idile Ijaade; Ọmọba Adetayọ Falilu
Adeọṣun ti idile Adeọṣun; Ọmọba Saburee Babajide Bakre ti idile Jamolu; Ọmọba
Sufian Ọlatunji Ṣoẹtan ti idile Jamolu, Ọmọba Akeem Abiọdun Agbaje atawọn min in.
Wọn ni ki Ọba Ọlaloko too waja
ni igbimọ afọbajẹ ẹlẹni mejila ti wa nilẹ lati ṣakoso eto yiyan ọba min in, ṣugbọn ti meje ti ku ninu wọn, ti won fi ku marun un.
A gbọ pe ṣe ni Demọla Bakre to
tun jẹ akọwe ẹbi Egiri fowo ra awọn igbimọ afọbajẹ naa, pe kawọn maraarun dibo
yan Saburee Bakre to jẹ ọmọ ẹgbọn ẹ, oun si nikan ṣoṣo ni Demọla Bakre fi ọna
alumọkọrọyi mu orukọ rẹ wọle fawọn afọbajẹ lai si tawọn mẹjọ to ku nibẹ.
Lẹyin ẹ la gbọ pe awọn idile
Egiri fogun ta pe awọn ko yan Demọla Bakre gẹgẹ bi olori ẹbi tabi aṣoju wọn
nidi ọrọ ọba ti wọn n du naa. Eyi ni wọn loo mu awọn mọlẹbi naa lọọ ṣepade
lagboole Egiri to wa ni Oke-Ido, Gbagura niluu Abẹokuta lati rii pe wọn yọ
Demọla Bakre, ṣugbọn ti wọn loo sọ pe ko sẹni to le yọ oun nipo naa, latari
madaru ti wọn loo fẹẹ ṣe.
A ti ẹ gbọ pe ṣe ni Demọla naa
ko awọn ọlọpaa atawọn babalawo kan lọ si Aafin Gbagura lati yẹ Ifa wo lori ẹni
ni ti yoo j'ọba naa, ti wọn si loun atawọn ti wọn jọ n da ilu naa ru ni wọn wa
nibẹ, lẹyin ẹ ni wọn loo jade sita, to si kede pe Saburee Babajide ni Ifa mu pe
yoo j'ọba naa lai si awọn adije yooku nibẹ.
Awọn ta a gbọ pe wọn tọwọ bọ'we
pe ki wọn yọ ọkunrin naa ni Ọmọba Adeọla Adeyẹmi ti mọlẹbi Ijaade; Ọmọba Waheed
Adeọṣun to jẹ akọwe mọlẹbi Egiri; Ọmọba Sufian Ṣoẹtan ti idile Jamolu; Ọmọba
Adam Ọpẹloyẹru ti idile Abọlade; ati Imaamu Jamiu Ogunwọọlu ti idile Ijaade.
Ninu awọn iwe ẹsun ti wọn fi
gbe ijọba ipinlẹ Ogun, Adajọ fẹyinti naa, Demọla Bakre, Ọba tuntun naa, awọn
adele ọba, awọn afọbajẹ, atawọn min in lọ sile ẹjọ, eyi to tẹ wa lọwọ lopin ọsẹ to
kọja yi ni wọn ti sọ pe ọna ti wọn fi yan Ọmọba Saburee Bakre ni ko ba ilana bi
wọn ṣe n yan ọba tuntun niluu Gbagura mu, to si tun tako ofin yiyan ọba nipinlẹ
Ogun.
Ọmọba Ṣarafadeen Ogunwọọlu, Ọmọba Saburi Adeyẹmi, Ọmọba Sufian Ṣoẹtan, Ọmọba Salihu Adetunji Nasir, Ọmọba
Kabiru Abọlade ati Ọmọba Wasiu Adeyinka ni wọn pe ẹjọ naa ti nọmba rẹ jẹ
AB/292/2019 pe bijọba ko ba gbe igbesẹ lati da awọn to wa nidi madaru naa lọwọ
kọ, o ṣee ṣe ko ṣakoba fun idagbasoke ilu lọjọ iwaju, ati pe wọn gbọdọ fi tawọn
alalẹ ṣe.
Awọn olupẹjọ naa ninu iwe ẹsun
yi tun n beere pe nibo gangan ni ile baba Demọla Bakre ati Saburee Bakre
l’Oke-Iddo, Gbagura wa, ti wọn si tun sọ fun wa pe wọn ti n wa ilẹ tabi ile lati ra fi ṣe
orirun wọn.
Bẹẹ ni wọn tun sọ pe gbogbo ọba ti
gomina ana, Ibikunle Amosun yan lati oṣu keji titi dasiko to fi gbe ijọba silẹ
nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun ti sọ pe ki wọn lọọ jokoo sile wọn, nitori pe
igbesẹ ti wọn ba yan wọn ko ba ilana oye jijẹ ipinlẹ Ogun mu, ṣugbọn ti wọn sọ
pe Demọla Bakre atawọn isọngbe ẹ sọ pe ofin naa ko kan ọba tawọn.
Meji lara awọn Oloye Agura ti
wọn lawọn naa ko fara mọ awọn nnkan to n ṣẹlẹ, to b'AWIKONKO sọrọ, awọn
eeyan naa ti wọn ni ka forukọ bo wọn laṣiri jẹ ko ye wa pe lati nnkan bi ọsẹ
mẹta sẹyin ni wọn ti gbe ofin tuntun jade pe dandan ni ki gbogbo idile to wa
niluu Gbagura wa maa yọju s'ọba n'Ipebi, ti wọn si gbọdọ mu awọn nnkan bii apo
raisi kan, ẹgbẹrun lọna aadọta, paali ọti ṣinaapu kan, gbogbo awọn nnkan wọnyii
ni wọn si sọ pe ko gbọdọ din ni ẹgbẹrun marundinlọgọta (75,000) naira.
Wọn lawọn idile ti wọn lọ ti
wọn ko mu nnkankan dani ni Demọla Bakre ko fun un laaye lati wọ Ipebi ri ọba,
ti wọn si lawọn to gbe nnkan dani ni wọn n fun laaye lati wọle ri ọba.
Nigba to n tako awọn ẹsun ti
wọn fi kan an, Demọla Bakre sọ pe ko si otitọ kankan ninu ẹsun ti wọn fi kan
oun, ati pe oun ko lọrọ lati ba oniroyin kankan sọ, tori pe awọn ti wọn gbe ẹjọ fun wa ti gbe ẹjọ naa lọ si kọọtu.
Adajọ feyinti naa jẹ ko di mimọ
pe boun yoo ba ti ẹ sọrọ, ile ẹjọ nikan loun ti le sọrọ, ṣugbọn to jẹ ko ye wa
pe ṣe ni ọrọ ipo ọba ti wọn n du dabi ọrọ oṣelu ni, tori pe eeyan kan ṣoṣo ni
yoo di ọba, to si jẹ pe ẹni tawọn afọbajẹ fa kalẹ niyẹn.
O tun fi ye wa pe toun yoo ba
ti ẹ fa eeyan kalẹ, oun lawọn ọmọ to le di ọba, ṣugbọn toun ko ṣe bẹẹ nitori pe
oun mọ ofin gẹgẹ bi adajọ fẹyinti, idi ni yii toun ko fi da si ọrọ ọba ti wọn n
du rara. O ni to ba jẹ ẹnikẹni ninu awọn ti wọn n sọrọ yi ni wọn fa kalẹ, oun
yoo ti wọn lẹyin, ati pe olowo lo n jẹ oye lasiko ta a wa yi, nitori pe ko sẹni to fẹẹ fi
akuṣẹ joye.
No comments:
Post a Comment