Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta
Ṣe lọrọ di boolọ o yago lọjọ Tọsde ọsẹ to
kọja yi nigba ti wọn ni tanka elepo nla kan deede ṣubu lulẹ lojiji ladugbo Oke-Ṣokori
niluu Abẹokuta ni nnkan bi aago mẹwaa kọja iṣẹju diẹ aarọ.
Ko si nnkan meji to ko ibẹru sọkan awọn
araalu, paapaa awọn ara agbegbe naa bi ko ṣe pe ọdun mẹjọ gbako ti tanka ṣubu lagbegbe naa ni eyi tun ṣẹlẹ. Ohun ta a gbọ ni pe ko ju bi ọjọ kẹta ti wọn
bura fun Gomina ana nipinlẹ Ogun, Ibikunle Amosun tan, ni tanka naa ṣubu, to si jo
ile ti ko din ni ogun ati ile epo nla kan ti wọn ṣẹṣẹ kọ sibẹ danu.
Ko din ni eeyan mẹẹdogun to ku sinu
ijamba lọdun naa lọhun, tọpọ awọn eeyan si farapa yannayanna lasiko naa.
Ohun ta a gbọ ni pe agbegbe Itọṣi ni
tanka ti wọn loo jẹ ileepo Dambold naa ti n bọ, to si n lọ si agbegbe Camp lati lọọ ja epo
fun wọn, Ṣugbọn nigba to de agbegbe Ori-Omi ni Ṣokori lo ya soju ọna Ita-Ẹkọ,
amọ ṣa, wọn ni bo ṣe n gun oju ọna naa to jẹ oke lọ, ni ijanu ẹ deede da iṣẹ
silẹ, to si mu ẹyin pada.
Lẹsẹkẹsẹ ni ọdọmọkunrin kan toun maa n
tẹle awọn awakọ tanka (motor-boy) ti sare bọ silẹ, to si bẹrẹ sii gbe igi sabẹ
taya lati da a duro, ko ma baa da wahala silẹ, ṣugbọn ti ko pada ri tanka naa
da duro.
Lẹsẹkẹsẹ lawọn mọto to n tẹle e lẹyin
ti bẹrẹ sii mu ẹyin rin pada lati sa asala fun ẹmi ara wọn, ṣugbọn lojiji lo ṣubu
lulẹ siwaju taisi kan, tawọn ero inu ẹ si ba ẹsẹ wọn sọrọ.
Bawọn to wa lagbegbe naa ṣe rii nkan to ṣẹlẹ yi lawọn eeyan ti bẹrẹ sii sa jade kuro ninu ile wọn, tawọn to ni ṣọọbu
sitosi si sare ti ṣọọbu wọn, ti wọn na papa bora, ko too di pe wọn ranṣẹ pe awọn
panapana lati wa duro nitosi.
Kopẹ ti wọn tun fi ranṣẹ sawọn oṣiṣẹ
mọnamọna pe ki wọn pa gbogbo ina agbegbe naa, ki wahala ma baa ṣẹlẹ.
AWIKONKO gbọ pe tori pe ọjọ Tọside
naa jẹ ọjọ gbale-gbata (environmental) ni ko jẹ kawọn olounjẹ lagbegbe naa tete
de lati dana ounjẹ, idi ni yii ti ko fi gbana, nitori ti wọn ni ko din ni olounjẹ mẹjọ to wa
lagbegbe iṣẹlẹ naa.
Nnkan to tun fẹẹ ko ibẹru sọkan awọn eeyan
ni bi olounjẹ kan to wa ladojukọ tanka to ṣubu yi ko ṣe tete ri ina ounjẹ pa,
to si mu kawọn eeyan binu lọ ba a ni ṣọọbu lati luu, ṣugbọn tawọn oṣiṣẹ sifu
difẹnsi gba a silẹ, ti wọn si le obinrin naa kuro ni ṣọọbu.
Lara awọn to kagbako ijamba ọdun mẹjọ
sẹyin to b’AWIKONKO sọrọ nibi iṣẹlẹ naa to kọ lati darukọ ẹ sọ pe oun ko
le gbagbe ọdun naa lọhun, tori pe ko din ni oṣu mẹfa toun lo lọsibitu pẹlu ọmọ
oun kan, tawọn jona mọle, ṣugbọn to jẹ pe ori lo koun yọ.
Ohun tawọn eeyan n sọ ni pe ṣe kii ṣe
pe afiṣe lọrọ naa to jẹ pe gbogbo igba ti wọn ba n bura fawọn gomina tuntun tan ni tanka
epo maa n ṣubu lagbegbe naa, ati pe Ọlọrun lo ko awọn yọ lọwọ eyi ti ko jẹ ko
gbana lojiji.
No comments:
Post a Comment