ṢẸGUN FIPA BA ỌMỌ ẸGBỌN Ẹ, ỌMỌDUN MẸRINDINLOGUN SUN N'IBAFO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, June 30, 2019

ṢẸGUN FIPA BA ỌMỌ ẸGBỌN Ẹ, ỌMỌDUN MẸRINDINLOGUN SUN N'IBAFO

Bi ile ẹjọ ba fi le fidi ẹ mulẹ pe ọdaran paraku ni Ọlawọyin Ṣẹgun ti wọn loo fipa ba ọmọ ẹgbọn ẹ sun niluu Ibafo lọjọ Ẹti to kọja yi, afaimọ ko ma jẹ pe ọdun mọkanlelogun ni yoo lo lọgba ẹwọn.

Ohun ta a gbọ ni pe Ṣẹgun lọ sile ẹgbọn ẹ to wa ni Mapara Makogi, Ibafo ni nnkan bi aago kan aabọ ọsan, nigba to si de bẹ, wọn ni ọmọdebinrin naa ta a forukọ bo laṣiri lo ba nile, tawọn obi ẹ ti lọ si ṣọọṣi.

Afaani ni wọn loo jẹ fun Ṣẹgun ti wọn lo ti n dọdẹ lati wa ọna lati fipa ba ọmọ naa sun lọjọ to ti pẹ. Lojiji la gbọ pe o ki ọmọdebinrin naa mọlẹ, to si bẹrẹ sii ko ibasun fun un.

AWIKONKO gbọ pe gbogbo bi ọmọdebinrin naa ṣe n janpata lati gba ara rẹ silẹ lọwọ Ṣẹgun ni wọn loo ja si pabo, ko da, ti wọn loo tun deyin mọ lọrun, ṣugbọn ti agbara Ṣẹgun pọ ju tiẹ lọ.

Bi Ṣẹgun ṣe mu toju ẹ kuro labẹ ọmọ naa ni wọn loo bẹrẹ sii bẹbẹ, tọmọ naa si loun ti gbọ. Bi awọn obi ẹ ṣe de lo sunkun sọ fun wọn nipa nnkan ti Ṣẹgun ṣe, eyi ni wọn loo ,u wọn gba tẹṣan ọlọpaa Ibafo lọ lati lọọ fẹjọ sun, ti wọn si lọọ gbe Ṣẹgun nile.

Iṣẹ ẹṣu ni wọn ni Ṣẹgun loo sun oun debi iwa buruku naa, ati pe lẹyin toun dide lori ọmọ naa loju oun too la, tori pe oun ko mọ nnkan to ṣẹlẹ. Bẹẹ lo bẹbẹ fun idariji.

Agbẹnusọ fawọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi fidi ẹ mulẹ pe ọga wọn, Basir Makama ti paṣẹ pe kawọn ọlọpaa to n ri si lilo ọmọ nilokulo tẹsiwaju iwadii, ki wọn si rii pe wọn foju Ṣẹgun bale ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI