Ile-iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Anambra ti sọ pe kawọn to n gbe mọto kaakiri opopona fọkanbalẹ tori pe ọwọ ti bẹrẹ sii tẹ wọn lẹyọ kọọkan.
Alukoro ile-iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Haruna Mohammed lo fidi iṣẹlẹ naa mulẹ pe ọwọ ti tẹ awọn ọdaran meji kan ti wọn ko niṣẹ meji ju ki wọn maa fibọn gba mọto lọwọ awọn eeyan lọ.
Awọn ọdaran naa ni, Ifeanyi Jude, ọmọdun marundinlọgbọn ati Okwudili Okoli toun jẹ ọmọ ọgbọn ọdun. Ohun ta a gbọ ni pe awọn ọlọpaa ti wọn yan si aarin gbungbun Onitsha ni wọn rọwọ to wọn.
Wọn ni mọto ayọkẹlẹ Toyota ti nọmba idanimọ ẹ jẹ HRH -01-NEN to jẹ ti Ọba Igwe tiluu Adazi Ani, iyẹn Igwe Robert Nwankwo ni wọn ji gbe.
Lai pẹ ni wọn lawọn ọdaran naa yoo foju bale ẹjọ.
No comments:
Post a Comment