ỌWỌ TẸ BAALE ILE MEJI TO N DIGUN JALE, DIẸ LO KU KI WỌN DANA SUN WỌN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, June 11, 2019

ỌWỌ TẸ BAALE ILE MEJI TO N DIGUN JALE, DIẸ LO KU KI WỌN DANA SUN WỌN

Diẹ lo ku kawọn araalu Umudimogo Ihiala dana sun awọn ọdaran meji kan ti wọn ni ogbologbo adigunjale paraku ni wọn, ati pe ko si ojumọ kan ki wọn ma lọọ digun ja awọn araalu naa lole, ti wọn si lawọn eeyan ko le sun asungbadun mọ.

 
Ṣe ni idunnu ṣubu lou ayọ wọn nigba tọwọ tẹ awọn baale ile meji naa lasiko ti wọn ṣẹṣẹ jale wọn tan.

 
A gbọ pe awọn oogun ti wọn fi n kun awọn ti wọn ba fẹẹ ja lole loorun ni wọn ka mọ wọn lọwọ, ti wọn si dana iya kogberegbe fun wọn.

Lẹyin o rẹyin la gbọ pe wọn lọọ fa wọn le awọn ọlọpaa lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI