ỌPẸ O! IROYIN AWIKONKO TI GBẸRẸGẸJIGẸ, ẸGBẸRUN LỌNA ỌGỌRUN MARUN LAWỌN TO NIFẸẸ WA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, June 17, 2019

ỌPẸ O! IROYIN AWIKONKO TI GBẸRẸGẸJIGẸ, ẸGBẸRUN LỌNA ỌGỌRUN MARUN LAWỌN TO NIFẸẸ WA

Yoruba bọ, wọn ni "Ka dupẹ lọwọ ẹni to ri ni, to m'ọju, eeyan kan ni ko wo ibi ti a wa rara", wọnyii gan an lọrọ to lọ n'ibamu pẹlu bi a ṣe ni awọn ẹgbẹrun lọna ọgọrun marun un (500,000) awọn to ti ka Iroyin AWIKONKO bayii.

Ki i ṣe mimọ ọn ṣe wa, bi ko ṣe oore-ọfẹ Ọlọrun ati ifẹ ẹyin ololufẹ ẹ wa, fun ifọwọsowọpọ ti ẹ ni pẹluu wa, bi ko ba si ẹyin ni, ko le si ile-iṣẹ AWIKONKO MEDIA CHANNEL to n gbe iroyin AWIKONKO jade ni gbogbo igba.

A n fi asiko yi gba a ladura pe 'Ẹ ko ni i mọ ikoro, bẹẹ ni ibanujẹ ko nii tọ si i yin. Ọmọ araye ko nii fi ẹgba fun un lounjẹ jẹ'. Bi a ba sọ pe ka maa ṣe adura lọ, ọrọ naa yoo gun lọ titi, ṣugbọn iyẹn ko ni ka ma sọ pe ile ati ọna yin ko nii daru lagbara Adẹdaa.

Pẹluu bi a ti ṣe ni awọn ẹgbẹrun lọna ọgọrun marun awọn to ti n tẹle wa, a wa n fi asiko yi mu da a yin loju pe, agbo wa ti fi ẹyin rin ni wa, a si ti lọọ mu agbara min in de lati maa tẹ ẹ yin lọrun ju ti tẹlẹ lọ, nipa awọn ọkan-o-jọkan iroyin wa.

Bi a ṣe n ki awọn to n polowo ọja wọn lori ikanni wa yi, bẹẹ la n dupẹ lọwọ awọn to n fun wa ni imọran itẹsiwaju ni gbogbo igba, paapaa ẹyin ti ẹ ko le ṣe ki ẹ ma ka iroyin wa lọjọ la n dupẹ lọwọ yin.

Ile-iṣẹ wa fi n muu da a yin loju pe laipẹ, a fẹẹ ṣi ẹrọ amohun-maworan, iyẹn Tẹlifiṣan Awikonko, nibi ti a o ti maa mu oriṣiriṣi iṣẹlẹ wa fun un bii ifọrọwerọ, awọn iṣẹlẹ kayeefi lawujọ, atawọn iroyin bo ṣe n lọ lawujọ wa kaakiri ilẹ Yoruba, ati orilẹ-ede Naijiria lapapọ.

Yatọ si pe kaakiri orilẹ-ede Naijiria ni wọn ti n ka Iroyin AWIKONKO, bẹẹ ni wọn tun n ka lawọn orilẹ-ede bii Brazil, Singap

Bakan naa la n fi asiko yi pe gbogbo ẹyin ti ẹ ni ile-iṣẹ nla-nla ati kereje, ẹyin ọlọja ati olokoowo nla pẹlu kereje, wi pe aaye ṣi silẹ fun un yin lati polowo ọja yin pẹluu wa, ti ẹ ko si nii kabamọ pe ẹ ba wa dowopọ.

Bẹẹ la tun n fi asiko yi pe awọn oloṣelu pe ikanni AWIKONKO yatọ si oju ti ẹ fi n wo o, nitori pe a ti gbẹrẹgẹjigẹ, nitori naa, ẹ lo anfaani wa lati gbe iṣẹ ati ipo yin larugẹ, ẹ ko si nii kabamọ.

Ẹ ṣẹun lọpọlọpọ.

Ẹ pade wa lori
Youtube: IROYIN AWIKONKO
Facebook Page: IROYIN AWIKONKO
Twitter: IROYIN AWIKONKO
WhatsApp:  IROYIN AWIKONKO 2

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI