Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi awọn gbajugbaja ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea tẹlẹ, Didier Drogba ati John Terry ti wa ni Papa iṣere Stamford Bridge ti Chelsea bayii ni imurasilẹ idije ifẹsẹwọnsẹ kan to fẹẹ waye lọjọ Sande tọ n bọ yi.
Idije naa ti wọn pe ni Soccer Aid game la gbọ pe ogunlọgọ awọn ololufẹẹ bọọlu kaakiri agbaye ti n mura silẹ fun, eyi ti wọn ni yoo ko owo jọ fawọn ọmọde lagbaye.
AWIKONKO gbọ pe awọn alakoso Good Morning Britain, Piers Morgan ati Susanna
Reid ni wọn yoo maa koju ara wọn nibi idije naa ti wọn sọ pe ajọ to n ṣe iranlọwọ fawọn eeyan lagbaye, UNICEF lo ṣagbekalẹ ẹ.
Lara awọn gbajugbaja atawọn ogbontarigi nidi ere bọọlu bii Michael Owẹn, Ẹric Cantona, Usain Bolt, Jamie Redknapp, Niall Horan, Drogba,
Sir Mo Farah, Mark Wright, James McAvoy ati Martin Compston ni yoo bọ sori papa lọjọ naa.
No comments:
Post a Comment