ỌNNỌGHẸN KỌWE FIṢẸ SILẸ, NI AARẸ BUHARI BA L'AWỌN KO FẸẸ MỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, June 10, 2019

ỌNNỌGHẸN KỌWE FIṢẸ SILẸ, NI AARẸ BUHARI BA L'AWỌN KO FẸẸ MỌ

 
Olori awọn onidajọ lorilẹ-ede Naijiria, Onidajọ Walter Ọnnọghẹn ti kọwe silẹ pe oun ko ṣiṣẹ ijọba mọ, ati pe asiko ti to foujn lati fẹyin ti nidi iṣẹ naa, to si ti fi ranṣẹ si Aarẹ Muhammadu Buhari.

Ana ti i ṣe Sande ni Aarẹ Buhari bu ọwọ lu iwe ifẹyinti naa, to si loun dupẹ lọwọ ẹ fawọn ipa to ti ko lẹka eto idajọ orilẹ-ede yii.

Ninu lẹta ti Aarẹ Buhari fi bu ọwọ lu iwe Onidajọ Ọnnọghẹn lo ti jẹ ko di mimọ pe ifiṣẹsilẹ naa yoo bẹrẹ lati ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un ọdun yi.

Bẹ o ba gbagbe, Aarẹ Buhari lo jawe lọọ jokoo silẹ ẹ fungba diẹ fun Onidajọ agba naa to bẹrẹ iṣẹ loṣu kẹta ọdun 2017 latari bi ko ṣe fi gbogbo awọn dukia ẹ to ni han sita nigba to fẹẹ gba ipo naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI