ỌMỌDUN MẸRINDINLOGUN DI ỌBA L'ONDO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, June 2, 2019

ỌMỌDUN MẸRINDINLOGUN DI ỌBA L'ONDO

Lẹyin aadọrun ọjọ ti ọmọdun mẹrindinlogun kan, Adeyẹọba Oloyede Adekọya ti wa ni yara Ipebi, wọn ti sọ ọ di ọba lẹkunrẹrẹ, ti ayẹyẹ nla igbade si n bọ lọna laipẹ.

Gbogbo awọn araaluu Okeluṣe to wa nijọba ibilẹ Oṣe nipinlẹ Ondo ni wọn ti n ki Kabiyesi tuntun naa, Ọba Adeyẹọba Oloyede Adekọya, Akighare II to jẹ Ojima Arujalẹ ti Okeluṣe ku oriire tuntun naa.

Si iyalẹnu, akẹkọọ ileewe girama keji ni Ọba Adeyẹọba Oloyede Adekọya, Akinghare II.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI