Ọjọ Fraide ọsẹ to kọja yi la gbọ pe ọwọ tẹ Adeṣọla ni nnkan bi aago mẹjọ aarọ lagbegbe Alagbado, ti wọn si oriṣiriṣi ibọn agbelẹrọ
mẹrin ati ọta ibọn mejidinlogoji ni gba lọwọ loju ẹsẹ ninu ọkọ bọọsi to ko awọn ọmọ ẹyin ẹ sii lati lọọ ṣiṣẹ ibi.
Agbegbe Amikanlẹ lọwọ ti tẹ wọn gẹgẹ bi ọga agba ile-iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekoo, Bala Ẹlkana ṣe sọ. O ni ọmọdun
marundinlaadọta ni Adeṣọla jẹ, to si jẹ ọmọ ẹgbẹ ikọ̀ alagbara kan to maa n gba ilẹ onilẹ, to
si tun n ṣiṣẹ agbanipa nipinlẹ Ogun ati Eko.
Loju ẹsẹ ti wọn laṣiri wọn ti tu lawọn ọmọṣẹ ẹ ti wọn jọ wa ninu mọto naa ti na papa bora, tawọn ọlọpaa ṣi n wa wọn dasiko yi.
Ninu ọrọ Adeṣọla lo ti sọ pe o lawọn to ran oun niṣẹ naa, tori pe iṣẹ toun fi n jẹun niyẹn, ati pe gbajugbaja loun nidi iṣẹ ajagungbalẹ nipinlẹ Ekoo ati Ogun.
No comments:
Post a Comment