ỌLỌPAA TI WỌN FI ORUKỌ ỌṢINBAJO LU NI JIBITI BU SẸKUN NITA GBANGBA (FIDIO) - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, June 16, 2019

ỌLỌPAA TI WỌN FI ORUKỌ ỌṢINBAJO LU NI JIBITI BU SẸKUN NITA GBANGBA (FIDIO)

Ọrọ buruku toun tẹrin nigba ti ọlọpaa kan bu sẹkun nita gbangba pẹluu bo ṣe sọ pe awọn ọmọ Yahoo fi orukọ igbakeji Aarẹ orilẹ-ede Naijiria lu iyawo ẹ ni jibiti owo to din diẹ ni miliọnu kan naira.

Ọlọpaa naa nibi to ti n ba awọn kan sọrọ ninu mọto lo ti jẹ ko ye wọn pe iyawo oun lo pade ẹnikan lori ayelujara, tẹni naa si loun n ṣiṣẹ ni ile-iṣẹ kan to jẹ ti igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, ati pe oun ṣetan lati ran an lọwọ.

Ẹni naa lo sọ fun obinrin naa pe ko fi akanti ile ifowopamọ si ẹ ranṣẹ soun, pe oun yoo fi miliọnu kan din lẹgbẹrun lọna aadọta (950,000) naira.

Ko pẹ to loo fi akanti naa ranṣẹ ni wọn bẹrẹ sii yọ owo ninu apo owo ile ifowopamọ si ẹ, to si n bẹbẹ fun iranlọwọ.

Ẹ wo fidio naa.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI