ỌGA ỌLỌPAA ORILẸ-EDE NAIJIRIA RAN AWỌN EEYAN LỌỌ BẸ AARẸ ỌNA KAKANFO LORI ETO AABO ILẸ YORUBA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, June 19, 2019

ỌGA ỌLỌPAA ORILẸ-EDE NAIJIRIA RAN AWỌN EEYAN LỌỌ BẸ AARẸ ỌNA KAKANFO LORI ETO AABO ILẸ YORUBA

Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta

Pẹlu nnkan to ṣẹlẹ yi, o ti n foju han bayii pe iwa ipaniyan, ijinigbe ati ai ni eto aabo to ti n koju ilẹ Yoruba lati bi ọdun meloo kan sẹyin bayi ti n fẹ di ohun igbagbe latari bi ọga ọlọpaa patapata lorilẹ-ede Naijiria ṣe ran awọn ọlọpaa ẹ pe ki wọn lọọ ṣepade pọ pẹluu Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams lori awọn iṣoro ati ipenija to n koju awọn eeyan.


Ọjọ Iṣẹgun Tuside ana lawọn eeyan naa gbera lọọ sile Iba Adams, ẹni to tun jẹ olori ẹgbẹ ajijagbara Oodua Peoples Congress, OPC ṣepade naa niluu Ekoo, ti wọn si n rababa bẹ ẹ pe dakun gba awọn eeyan lọwọ awọn ajinigbe.

Bẹ o ba gbagbe, lai pẹ yi ni awọn ẹgbẹ OPC sọ pe awọn yoo bẹrẹ sii koju awọn Fulani ti wọn n ji awọn eeyan gbe, tawọn yoo si bẹrẹ sii pa wọn pẹluu oogun abẹnugọngọ tawọn gbojule.
 
Insecurity: IG parleys with Aare Gani Adams 
Aarẹ Adams ti wa a sọ pe oun ti ṣetan lati fọwọsowọpọ pẹluu awọn ọlọpaa lati yanju gbogbo iṣoro naa, tawọn yoo si ṣe aṣeyọri lori eto aabo.

Nigba to n dahun ibeere lọwọ awọn oniroyin, paapaa ti ile-iṣẹ iroyin BBC Yoruba, O ni ijomitoro lori ọ̀rọ̀ eto aabo ilẹ Yoruba ni ipade naa da le lori, ati pe kii ṣe ohun teeyan kan le maa sọ lori ẹrọ ibara ẹni sọrọ.

Ṣaaju ninu ifọrọrọwanilẹnuwo kan pẹlu BBC Yoruba lori eto aabo, Gani Adams sọ pe ẹgbẹ OPC ko le da si ọrọ aabo Naijiria ti ijọba ko ba pe wọn si i.
 
Lori eyi, Iba Adams jẹ ko di mimọ pe "Ọlọpaa to ba mọ pe oun fẹ ṣe aṣeyọri kun aseyọri gbọdọ ba ẹgbẹ OPC ṣe papọ. Ọga ọlọpaa patapata ran awọn to wa lati ṣe ipade pẹlu OPC pe oun nilo iranlọwọ ẹgbẹ naa ni.

"A si jọ fẹnuko nibi ipade naa pe a jọ maa ṣiṣẹ pọ, ṣugbọn gbogbo nkan lo ni eto. Gẹgẹ bi a ti ṣe pẹluu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko lori ọrọ Badoo to n paayan nigba naa lọhun, a ti ṣetan lati ran wọn lọwọ, ọwọ wọn lo wa a ku si bayii, nitori pe ọrọ ijọba kii ya bọrọ nigba miiran, bo tilẹ jẹ pe awọn jọ ṣepade."

Ṣaaju asiko yi la gbọ pe ẹgbẹ kan t'oun naa n jijagbara nilẹ Yoruba, iyẹn Ẹgbẹ Agbẹkọya sọ fun fawọn oniroyin pe "oogun abẹnugọngọ nikan ni ọna abayọ si ọrọ awọn ajinigbe", ati pe awọn ti ṣetan lati koju wọn, ti ijọba ba le fun wọn ni aaye lati ṣe bẹẹ.

Lori boya o ṣeeṣe ki ẹgbẹ OPC ati ẹgbẹ ajijagbara Agbẹkọya jọ ṣiṣẹ pọ lori eto aabo, Aarẹ Adams sọ pe ẹgbẹ Agbẹkọya naa ni iwulo fun ilẹ Yoruba lori eto aabo.

"Ọrọ to wa nilẹ yii kii ṣe ti OPC nikan, a fẹ ri i daju pe gbogbo awọn ẹgbẹ to ni nkan ṣe pẹlu eto aabo lati jẹ ki wọn wulo. Pẹlu ifọwọsowọpọ awọn ọba ati alaga ijọba ibilẹ awọn gomina."

bẹẹ lo tun sọ pe ipade apero nla kan n bọ laipẹ 'Yoruba Summit' lorukọ ẹ, nibi ti gbogbo ẹgbẹ to ni nkan ṣe pẹluu eto aabo yoo ti jiroro lori eto aabo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI