Fidio kan to n lọ kaakiri ori ayelujara bayii ni ti ọdọmọkunrin kan to loun lo ọdun mẹtala nilẹ Europe lati maa fi ṣiṣẹ awọn to n gbe egboogi oloro lati fi ri owo jẹun, to si jẹ pe owo toun ri loun fi n ranṣẹ sile fawọn mọlẹbi oun.
Ipinlẹ Delta la gbọ pe iṣẹlẹ kayeefi naa ti waye.
Ohun ta a gbọ ni pe ọdọmọkunrin naa fun odindi ọdun mẹtala to lo loke okun lo fi n fowo ranṣẹ sile pe ki wọn ba oun kọ ile toun yoo de si, ṣugbọn nigba ti yoo pada de, awawi ni wọn n sọ lẹnu.
Pẹluu ibinu lọkunrin naa fi n sọrọ, to si n bu sẹkun sọrọ, to si fẹẹ le ya were.
Fidio naa re e o
No comments:
Post a Comment