Bi ere, bi awada lawọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn lọjọ Tọside ana, nigba tọwọ awọn ọlọpaa to n ri si iṣẹlẹ pajawiri, iyẹn Rapid Respond Squared rọwọ to ọkunrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni School Boy, ẹni ti wọn loo gbajumọ daadaa nidi iṣẹ Danfo wiwa.
Ohun ta a gbọ ni pe ṣe ni School Boy fi oju ọna ti ẹ silẹ, to si lọọ doju awọn mọto to n bọ lodi keji, iyẹn lagbegbe Ọpẹbi niluu Ekoo, ko to o lọọ ko sọwọ awọn ọlọpaa yii.
Bọwọ ṣe tẹ ẹ la gbọ pe o sare bọ silẹ ninu Danfo ẹ, to si n rababa bẹ awọn ọlọpaa naa, ṣugbọn tawọn yẹn yari pe afi ko foju winna ofin.
Ipakọ ẹ la gbọ pe awọn ọlọpaa naa atawọn eeyan to wa nibẹ n wo lọ lọọkan lasiko to n salọ.
Nibẹ ni wọn ti pe mọto ti wọn ma fi n wọ mọto, iyẹn Janwe lati wọ mọto School Boy lọ si ọgba wọn, ti wọn si n reti ẹ lati wa a kawọn pọyin rojọ.
No comments:
Post a Comment