O MA ṢE O: ỌMỌDUN MEJIDINLOGUN KU LẸYIN ỌSẸ KẸTA TO ṢEGBEYAWO ALARINRIN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, June 25, 2019

O MA ṢE O: ỌMỌDUN MEJIDINLOGUN KU LẸYIN ỌSẸ KẸTA TO ṢEGBEYAWO ALARINRIN


Bawọn kan ṣe n sọ pe Ọrọ naa kii ṣoju lasan, yoo lọwọ aye ninu, bẹẹ lawọn kan n sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe ẹlẹgbẹ ni ọdọmọbinrin ẹni ọdun mejidinlogun kan, Chinwendy Promise Ifeabunandu ti wọn lẹyin ọsẹ kẹta to ṣegbeyawo alarinrin pẹlu ọkọ ẹ niku mun un lọ.

Iyalẹnu niku ẹ ṣi n jẹ fun ọpọ awọn eeyan, paapaa awọn mọlẹbi ẹ titi dasiko ti a kọ iroyin yi tan.

 
Ohun ta a gbọ ni pe, ọjọ kejidinlogun oṣu kẹrin ọdun yi ni Chinwendu ṣegbeyawo pẹluu ọkọ ẹ, Chukwuebuka Ifeabunandu, ṣugbọn to jẹ pe ọjọ kọkandilogun oṣu karun lo jade laye lẹyin aisan ranpẹ kan ti wọn loo kọluu.

 
Ọpọ owo la gbọ pe wọn ti na le ọmọbinrin naa lori lọsibitu, ko too di pe ọlọjọ de baa, to si gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra.

Ọkan lara awọn ẹgbọn ẹ, Nwakanwa Okafor nigba to n sọrọ lori iku aburo ẹ, o ni iku tẹnikẹni ko lero ni, to si da gbogbo mọlẹbi sinu ibanujẹ.

AWIKONKO gbọ pe ilu ọkọ ẹ to wa ni abule Nnulukwu, Ichida nijọba ibilẹ Aniocha, ipinlẹ Anambra ni wọn yoo sin Chinwendu lọjọ Satide to n bọ yi, iyẹn ọjọ kọkandinlọgbọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI