Bo tilẹ jẹ pe iwaddi awọn ọlọpaa ṣi n lọ lọwọ lori idi ti olukọ ile ẹkọ giga Karish college to wa niluu Kawaji, ipinlẹ Kano ṣi n lọ lọwọ, ṣugbọn sibẹ, kayeefi niku ọkunrin naa ṣi n jẹ fawọn araadugbo, paapaa awọn ti wọn jọ n gbe inu ile.
Ni nnkan bi aago mẹsan an alẹ ana, Fraide la gbọ pe awọn araadugbo naa lọọ wo n nile, nigba ti wọn sọ pe wọn ko rii ko jade bo ṣe maa n jade sita, eyi ti wọn loo mu ifura dani.
Bi wọn de ẹnu ọna yara ẹ, la gbọ pe wọn kan ilẹkun, ṣugbọn ti wọn ko gbohun kankan, eyi lo mu ki wọn lọọ gba oju fere wo inu ile lati mọ nnkan to n ṣẹlẹ, iyalẹnu lo jẹ pe oku ẹ ni wọn ba loke faanu to so ararẹ kọ sii.
Loju ẹsẹ ni wọn ti lọọ ranṣẹ pe awọn ọlọpaa, ti wọn si ja ilẹkun wọnu yara, ko too di pe wọn gbe e bọ silẹ.
A ti ẹ gbọ pe inu yara lawọn eeyan n wo kaakiri boya wọn yoo ri iwe to kọ silẹ gbẹyin nipa idi to fi gbẹmi ara rẹ lojiji, ṣugbọn ti wọn ni wọn ko ri nnkan to jọ bẹẹ titi dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan.
Yara itẹkusi ti osibitu Muhammad la gbọ pe wọn lọọ gbe oku ẹ si digba tawọn mọlẹbi ẹ yoo fi de, ta a ko si ti i gbọ nnkankan min in kọja eyi ti a kọ yi lọ.
No comments:
Post a Comment