Titi di bi ẹ ti n ka iroyin yi lọrọ iku ọdọmọbinrin agunbanirọ kan ti wọn pe ni Oghomwen Omoruyi Honour ṣi n jẹ kayeefi fawọn eeyan, paapaa awọn ọrẹ rẹ ti wọn jọ n sin orilẹ-ede baba wọn.
Ipinlẹ Ekiti la gbọ pe Honour, ọmọ bibi ipinlẹ Ẹdo naa ti n sin orilẹ-ede baba ẹ, lẹyin ti wọn gbe e lati ipinlẹ Adamawa wa sibẹ.
A gbọ pe igbe ori fifọ ni wọn sọ pe Honour n ke, ko too di pe o lo oogun kan ti wọn pe ni paracetamọl, to si jẹ pe ko pẹ to lo oogun naa lo bẹrẹ sii pofolo, to i daku.
Ere ni wọn lawọn to wa nibẹ kọkọ pe e, eyi to mu ki wọn gbe e digba-digba lọ si ọsibitu, ṣugbọn ohun ta a gbọ ni pe oju ọna ni akẹkọọ jade tile ẹkọ gbogboniṣe ti Auchi naa dakẹ si.
No comments:
Post a Comment