Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, iya agba ẹni aadọta kan ti ayẹwo fidi ẹ mulẹ pe o ti ko aarun aṣekupani nni, Ẹbola ti jade laye.
Ọjọ Tọside onii ni ile-iṣẹ eto ilera ti orilẹ-ede Uganda fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin pe iṣẹlẹ ẹlẹekeji re e latigba ti wọn ti ko aarun naa wọle lati orilẹ-ede olominira ti Congo.
Wọn ni iya agba naa to fi ọmọ-ọmọ to jẹ ọmọdun-marun un silẹ laye lọ, ta a si gbọ pe wọn ti n gbe igbesẹ lati sin mama naa si Kaṣesẹ.
No comments:
Post a Comment