Iroyin ti ko dun mọ ẹnikẹni
ninu ni ti ayederu oogun iba (malaria) kan ti wọn loo ṣekupa akẹkọọ ile ẹkọ fasiti
tipinlẹ Ẹnugu lọjọ Fraide ijẹta, ta a si gbọ pe ipele to kẹhin ni akẹkọọ naa wa.
Ojeh Cynthia Nnenna ni wọn pe orukọ akẹkọọ naa to rẹwa daadaa, ko da a,
ti wọn lawọn ọkunrin maa n duu pe lati fẹ nigba to wa laye. Ẹka ikẹkọọ iṣiro (Accounting) ni wọn loo wa nipele to gbẹyin.
A ti ẹ gbọ pe ko pẹ to ba ọkan
lara awọn ọrẹ rẹ sọrọ tan lori ikanni ayelujara ibara-ẹni-sọrọ (WhatsApp) pe
oun loogun kan, ti oogun naa si n da inu oun ru niku wọle muu lọ wẹrẹ.
Ẹkunrẹrẹ bo ṣe ra oogun naa,
ati bo ṣe lo o la gbọ pe o ṣalaye fun ọrẹ rẹ naa, to si sọ bi oogun naa ṣe n ko
irora ba agọ ara oun ru.
Cynthia ṣalaye bi wọn ṣe juwe
ogun naa fun un nile oloogun to lọ.
No comments:
Post a Comment