NITORI OMIYALE: IGBAKEJI GOMINA IPINLẸ OGUN BANUJẸ NITA GBANGBA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, June 9, 2019

NITORI OMIYALE: IGBAKEJI GOMINA IPINLẸ OGUN BANUJẸ NITA GBANGBA

Oluwaṣeun Boye

Ko sẹni to ri Gomina ipinlẹ Ogun, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ-Oyedele bo ṣe n ṣe lọjọ Fraide to kọja yi, ti ko ni i mọ pe inu ẹ ko dun rara, latari ojo arọọrọda to rọ lọjọ Tọside ijẹrin, to si fa omiyale lawọn agbegbe kan nipinlẹ naa.

Ni nnkan bi aago marun irọlẹ la gbọ pe ojo nla naa bẹrẹ, to si rọ di nnkan bi aago mẹsan alẹ, ko too lọ silẹ diẹ, ojo la gbọ pe o ṣọṣẹ lawọn agbegbe kaakiri ipinlẹ Ogun, paapaa niluu Abẹokuta.

Eyi lo mu ki igbakeji Gomina naa, Salakọ-Oyedele lewaju awọn aṣoju ijọba lati lọọ wo awọn agbegbe tijamba ti ṣẹlẹ nipa omi to yawọ ile wọn.

Nigba to n banujẹ sọrọ, igbakeji Gomina fi aidunu sọrọ pe ibanujẹ lo maa n jẹ foun nigba toun ba n ri iru awọn iṣẹlẹ yi, to si maa n kan oun lominu pupọ lawọn asiko toun ba gba agbegbe tomiyale ba ti ṣọṣẹ kọja.

Nibẹ lo ti gbawọn araalu lamọnran pe ki wọn dẹkun lati maa da idọti ati panti, tabi yagbẹ sinu awọn kọta to n gbe omi kaakiri, nitori pe awọn nnkan naa lo n fa akoba fun omiyale julọ.


O lawọn nnkan to tun n awọn nnkan wọnyi ni bi ko ṣe ti aisi agbara to to lati ṣatunṣe awọn ibi to yẹ, lati le dẹkun iru awọn ijamba bayii.

Onimọ-ẹrọ Salakọ-Oyedele jẹ ko ye ọpọ awọn eeyan pe ko si nnkan meji to n fa awọn akoba bayii, bi ko ṣe ti awọn idọti tawọn eeyan n da sinu odo, kọta atawọn ibi ti omi n gba kọja, nitori pe bi omi ko ba ri aaye lọ daadaa, yoo gba ori ilẹ, ti yoo si ṣakoba fawọn ile to ba wa nitosi.

Bakan naa lo tun jẹ ko di mimọ pe aifi aaye silẹ fun agbara awọn to n kọ ilẹ tun pẹlu awọn nnkan to n ṣakoba fun omiyale, to si gbawọn eeyan lamọnran pe ki wọn rii daju pe wọn n fi aaye omi silẹ bi wọn ba n kọ ile wọn.

O wa a fi da wọn loju pe ijọba ipinlẹ Ogun yoo forikori pẹlu ijọba apapọ orilẹ-ede yi lati da si, ki wọn si le wa ọna abayọ to ba yẹ lati dẹkun awọn wahala naa.

Nigba toun naa n sọrọ, Onimọ-ẹrọ Kayọde Ademọlakẹ to jẹ akọwe agba lẹka to n ri sọrọ iṣẹ akanṣe ati idagbasoke (Permanent Secretary, Ministry of Works and Infrastructure) sọ pe pupọ ninu awọn kọtati omi n gba kọja ni wọn ko fẹ to bo ṣe yẹ lati gba omi rẹpẹtẹ.

O wa a lawọn yoo bẹrẹ eto idanilẹkọọ laipẹ lati dawọn araalu lẹkọọ to ye kooro nipa bi wọn yo o ṣe maa da ilẹ ati idọti nu, ti ko si nii fa ipalara fun wọn.

Ṣaaju asiko yi ni Iyalọja ọja Gbangba, Alaaja Abibat Akanbi rawọ ẹbẹ sijọba pe ki wọn bawọn wa atunṣe sawọm ibi ti agbara n gba kọja yi, ki wọn si tare ẹ sọna min in ti ko ni maa ṣakoba fun, bẹẹ lo tun bẹbẹ pe kijọba bawọn foju aanu tun awọn ọja kaakiri ṣe lati dun un wo loju.

Lara awọn ibi ti omiyale ti ṣọṣọ ni: Igbore si Ijẹja river, Isalẹ Ọja Kutọ, Ọja Gbangba to wa ni Iyana Mọṣuari nijọba ibilẹ Abeokuta South.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI