Afaimọ ko ma jẹ pe ajọ INEC yoo pada kan abuku bi wọn ko ba tete da iwe ẹri mo yege sipo Sẹnetọ, eyi ti ajọ INEC gba lọwọ Gomina ana nipinlẹ Imo, Rochas Okorocha loṣu meji sẹ pada fun.
Ana, Fraide ni ile ẹjọ giga niluu Abuja ti Onidajọ Abang gbe idajọ naa kalẹ pe ki wọn lọọ da orukọ Okorocha pada sinu orukọ awọn to yege ninu idibo ọjọ kẹtalelogun oṣu keji ọdun yi gẹgẹ bi Sẹnetọ.
Ile ẹjọ naa jẹ ko di mimọ pe ajọ INEC ko laṣẹ lati di iwe ẹri Okorocha mu nitori pe oun lo jawe olubori lasiko idibo.
No comments:
Post a Comment