NITORI IPO NLA MEJI, IDAAMU DE BA GOMINA DAPỌ ABIỌDUN L'OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, June 6, 2019

NITORI IPO NLA MEJI, IDAAMU DE BA GOMINA DAPỌ ABIỌDUN L'OGUN

Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta
Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi lọwọ, afaimọ ko ma jẹ pe rederede nijọba Gomina tuntun nipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun yoo fi pari saa ijọba ẹ yi, pẹlu bi wọn ṣe lawọn alagbara to ṣagbatẹru ẹ to fi wọle ko ṣe fii lọrun silẹ, paapaa lori awọn ipo nla meji kan to kọ lati yan, iyẹn akọwe ijọba (SSG) ati olori awọn oṣiṣẹ gomina (Chief of Staff).
A gbo pe ipo nla meji naa ni wọn lawọn alagbara nidi oṣelu n ja si pe awọn lawọn yoo yan awọn ti yoo di ipo naa mu, ti wọn si ni afi kawọn Ijẹbu ati Ẹgbado pin-in laarin ara wọn, ṣugbọn ti wọn lawọn Ijẹbu fariga pe awọn lawọn yoo gba ipo mejeeji.

Awọn agba oṣelu bii Aṣiwaju Tinubu, Oloye Oluṣẹgun Ọṣoba, Ọjọgbọn Yẹmi 
Ọṣinbajo, Ọba Sikirulai Adetọna to jẹ Awujalẹ tilẹ Ijẹbu, Sẹnetọ Sọlọmọn Adeọla Yayi, Ọtunba Gbenga Daniel atawọn min ni wọn n ja du ẹni ti yoo di awọn ipo yi mu, tonikalu wọn si ni ẹni ti wọn fẹẹ fa kalẹ.

AWIKONKO gbọ pe awọn Ijebu n ja fun pe dandan ni kawon gba ipo akọwe ijọba ati olori awọn oṣiṣẹ gomina, ti won si ni ko ba ilana ofin mu pe ki ilu kan ṣoṣo di ipo mẹta akọkọ, iyẹn Gomina, Akọwe ijọba ati olori awọn oṣiṣe gomina mu.

Ohun ta a gbọ ni pe kii ṣe wahala kekere ni wọn lawọn alagbara yi n ba Gomina Dapọ Abiọdun fa lati ma ṣe foju wọn gbolẹ, eyi gan an ni wọn loo jẹ ẹfọri fun Gomina tuntun to ṣẹṣẹ lo ọjọ mẹjọ lori ipo, ti ko si mọ ẹni ti yoo tẹle ninu awọn oloore wọnyii.

Yatọ si eyi, a tun gbọ pe ipo abẹnugan ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun naa tun jẹ eyi to n kan Gomina Abiọdun lominu, ta a si gbọ pe ọkan pataki lara awọn ọnọrebu ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Ọnọrebu Olumide Ẹlẹmide ni wọn ti pari eto fun lati lo.

Eyi ti wọn lo n jẹ kayeefi ni bo tun ṣe jẹ pe awọn ọmọ ẹyin Gomina ijẹta, Ọtunba Gbenga Daniel lo pọ ju ninu ijọba tuntun yi, ti wọn si ni ṣe lo dabi ẹni pe OGD lo pada sipo gomina, to si dabi ẹni pe wọn fi Dapọ Abiọdun di gẹrẹu lasan ni.

Ipade nla ni wọn lawọn kan ko ara wọn lọọ ṣe nile Awujalẹ lọjọ Fraide ọsẹ to kọja yi, nitori ta a gbọ pe ida aadorin (70%) ipo lawọn Ijẹbu n ja fun ninu ijọba yi, ki wọn si pin ida ọgbọn ipo yooku saarin Ẹgba ati Ẹgbado, ṣugbọn ti wọn lawọn Ẹgba yari pe ko le ri bẹẹ.
Ahesọ kan to ti ẹ ta si AWIKONKO leti laipẹ yi ni pe Gomina Abiọdun ti bu ọwọ luu Ọtunba Bimbọ Ashiru to jẹ kọmiṣana fọrọ eto ọrọ aje ati ileeṣẹ nla-nla (Commerce and Industry) gẹgẹ bi akọwe ijọba, bẹẹ naa lo tun bu ọwọ lu Ọnọrebu Salisu Shuiab gẹgẹ bi olori awọn oṣiṣẹ Gomina (chief of staff), ti wọn ni yoo si kede wọn lọjọ Mọnde to koja yi, ṣugbọn ti ko pada ṣe ba a ṣe gbọ.
Ohun to ti ẹ tun n jẹ ki ẹru ma a ba ọpọ araalu titi di asiko yi ni bi Ọmọba Dapọ Abiọdun ko ṣe tii ri aṣẹ gidi kan pa, paapaa lọjọ ti wọn bura fun un titi di oni, to si jẹ pe ohun to n tẹnumọ ni pe ijọba oun yoo mu ayipada gidi de ba ipinlẹ Ogun.
Ibeere ti wọn lawọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Ogun n beere lọwọ ara wọn ni pe ṣe kii ṣe pe awọn ti ko sọkọ gbajuẹ (one chance) bayii nigba ti Gomina Dapọ Abiọdun ko le sọ pato ibi ti iṣẹ ti fẹẹ bẹrẹ ni pẹrẹu.
Fawọn to ba mọ bi nnkan ṣe n lọ nipinlẹ Ọyọ ati Ekoo, wọn yoo mọ pe Gomina Ṣeyi Makinde tipinlẹ Ọyọ sọ pe oun ti ṣetan lati yanju wahala LAUTECH to si ti paṣẹ pe ki ẹkọ ọfẹ bẹrẹ lati ileewe alakọbẹrẹ titi de girama, to si tun ti ṣi ọna ti Gomina Ajimọbi ti pa fun ọdun mẹjọ, bẹẹ lo tun ni ipinlẹ Ọyọ ko le san ẹgbẹrun lọna ọgbọn gẹgẹ bi owo oṣu, bakan naa lo tun loun ko fẹẹ ri ẹgbẹ onimọto NURTW.
Wọn ni kaka ki Ọmọba Dapọ Abiọdun sọrọ lori awọn wahala to n ṣẹlẹ to ba nilẹ, ipade ati abẹwo lo n ṣe kaakiri, ti wọn si loo yẹ ko ti  mọ ibi to n lọ gangan laarin ọgọta ọjọ to ti n gbaradi, iyẹn ni kete ki ajọ INEC kede ẹ.
Yatọ si pe ko kede awọn ti yoo ba a ṣiṣẹ pọ, wọn ni ko sọ nnkankan lori wahala awọn ileewe giga MAPOLY/MAUSTECH ati Ogun Poly; TASUED ati TASCE, eyi ti wọn lẹru ti bẹrẹ sii bawọn eeyan pe iru eeyan wo lawọn tun dibo fun yi.
Ninu iroyin min in lati gbọ pe ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun ti daba pe ki gbogbo awọn ọba marundinlọgọrin ti Gomina ana, Ibikunle Amosun ti yan gbagbe ipo naa, nitori pe ọna ti wọn gba yan wọn ko ba ilana ati ofin mu, ati pe pupọ ninu wọn ni ko tọ si ipo ọba.
Siwaju sii ni wọn tun dabaa pe ki gbogbo awọn alaga ijọba ibilẹ idagbasoke patapata ti Gomina Amosun yan ni kawọn naa lọọ rọkun ile wọn, tori pe wọn ko niṣẹ kankan ti wọn n ṣe.
Ṣa o, igbagbọ ṣi n fidi ẹ mulẹ pe Gomina Abiọdun yoo ṣe daradara kọja oju tawọn eeyan fi n wo o lasiko yi, tori pe kii ṣe pe ṣe lo wa jale nijọba, ati pe ọgbọn ati iriri ẹ nipa eto ọrọ aje lo n mu bọ lati fi sọ ipinlẹ Ogun di ipinlẹ akọkọ nilẹ Afrika to dara julọ, tawọn oyinbo yoo si maa wọle wa a da ileeṣẹ nla-nla silẹ.

2 comments:

  1. Awikonko e ku ise ilu olorun atun bo ma so agbara yin di otun..
    Ipinle ogun oni baaje.
    Olorun a ba wa jogun ogbon ati imo oye fun gomina wa tuntun,igba e atuwa Lara oo.

    ReplyDelete

PÍN-IN KÁÀKIRI